Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 9, 2013
SOUTH KOREA

Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Ya Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun Sọ́tọ̀ Kúrò Lára Àwọn Ọ̀daràn

Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Ya Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun Sọ́tọ̀ Kúrò Lára Àwọn Ọ̀daràn

Ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea mú kí nǹkan rọrùn díẹ̀ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Lọ́nà wo? Wọ́n kó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù.

Ìpàdé tí aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Korea ṣe pẹ̀lú òṣìṣẹ́ ìjọba kan tó jẹ́ ọ̀gá ní Àjọ Tó Ń Kọ́ni Láti Jáwọ́ Nínú Ìwà Burúkú nílẹ̀ Korea ní December 2012 ló bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Bàbá kan tí ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀ torí ọmọ rẹ̀ wà lẹ́wọ̀n àtàwọn aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòókù ṣàlàyé pé inú yàrá kan náà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ni wọ́n sábà máa ń fi àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí sí pẹ̀lú àwọn ọ̀daràn paraku. Láàárín oṣù márùn-ún lẹ́yìn tí wọ́n ṣèpàdé yẹn, ohun tó ju ìdá méje nínú mẹ́wàá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n ni wọ́n kó kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù, wọ́n sì fi wọ́n sí yàrá kan náà pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn.

Ó ti pẹ́ tí ìjọba ti ń fi àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n. Tipẹ́ ni ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ti ń fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti gbé ohun ìjà torí ó ta ko Ìwé Mímọ́. Lọ́wọ́lọ́wọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ló wà lẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Láti ohun tó lé ní ọgọ́ta (60) ọdún sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógún (17,000) ló ti lọ sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Ìdí ni pé òfin sọ pé dandan ni kí gbogbo àwọn ọkùnrin tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) sí márùndínlógójì (35) lọ sógun.

Kì í ṣe ohun tuntun pé kí ilé ẹjọ́ ti rán àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ mẹ́ńbà ìdílé kan náà láti ìran dé ìran lọ sẹ́wọ̀n kan náà rí. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń jẹ́ Seungkuk Noh, tó jáde lẹ́wọ̀n lọ́dún 2000 lẹ́yìn ọdún mẹ́ta sọ pé, “Ẹ̀wọ̀n kan náà tí wọ́n rán bàbá mi lọ nígbà tí wọ́n kéré ni wọ́n rán èmi náà lọ, bí nǹkan sì ṣe rí níbẹ̀ nígbà tí bàbá mi ṣẹ̀wọ̀n náà ló ṣì rí.” Lóde òní, oṣù méjìdínlógún (18) ni ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gbà láyè láti ṣiṣẹ́ ológun sábà máa ń lò lẹ́wọ̀n, ìjọba South Korea ò sì ṣètò àfidípò kankan fún iṣẹ́ ológun.

Ẹni ọdún mọ́kànlélógún (21) ni Ho Gyu Kang nígbà tí wọ́n rán an lọ sẹ́wọ̀n torí ó kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun. Ìgbà àkọ́kọ́ tó máa kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ nìyí. Ọ̀gbẹ́ni Kang sọ pé, “Ẹ̀rú bà mí gan-an nígbà yẹn, ọkàn mi ò sì balẹ̀.” Wọ́n fi òun àti ọ̀dọ́kùnrin míì tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí síbì kan náà pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́wọ̀n kan tó ti dàgbà, tí àwọn lọ́gàálọ́gàá ti gbà pé wọn ò lè yíwà pa dà. Apààyàn àti ọmọọ̀ta làwọn míì nínú wọn.

Látìgbà tí wọ́n bá ti fi àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí sẹ́wọ̀n títí wọ́n á fi jáde, ṣe làwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù wọ́n máa ń lù wọ́n nílùkulù, wọ́n sì máa ń ṣohun tó máa bà wọ́n nínú jẹ́, torí wọ́n sábà máa ń ju àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí lọ lọ́jọ́ orí. Ṣe ni wọ́n máa ń dájú sọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n, tí wọ́n sì máa ń fìyà jẹ wọ́n, ìyẹn kì í sì í jé káwọn Ẹlẹ́rìí lè ṣe ìjọsìn wọn, bíi kí wọ́n gbàdúrà tàbí kí wọ́n dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, tọ́dún ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ló ti jìyà lọ́wọ́ àwọn ọ̀daràn tí wọ́n jọ wà lẹ́wọ̀n, tí wọ́n sì pa á mọ́ra.

Bí wọ́n ṣe ya àwọn ẹlẹ́wọ̀n sọ́tọ̀ bá ohun tí ìjọba àpapọ̀ sọ mu. Bí ìjọba ilẹ̀ South Korea ṣe kó ọ̀pọ̀ àwọn tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù yìí bá ìlànà tí ìjọba àpapọ̀ fi lélẹ̀ lágbàáyé mu nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe àwọn tó wà lẹ́wọ̀n, bí èyí tó wà ní Àpilẹ̀kọ 8 nínú ìlànà tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè ṣe nípa bó ṣe yẹ kí ìjọba máa ṣe àwọn tó wà lẹ́wọ̀n. Ìjọba ilẹ̀ South Korea tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ohun tí orílẹ̀-èdè Gíríìsì tó jẹ́ ara Àwùjọ Àwọn Orílẹ̀-èdè Ilẹ̀ Yúróòpù ṣe lógún ọdún sẹ́yìn nígbà tí Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ààbò àti Ètò Ìdájọ́ lórílẹ̀-èdè náà fọwọ́ sí i pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù. Lọ́dún 1992, Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ààbò sọ àgọ́ àwọn ológun kan tó wà ní Sindos, nílùú Tẹsalóníkà di ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n á máa fi àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan sí. Ìròyìn kan sọ pé “bí Iléeṣẹ́ Ìjọba Tó Ń Rí sí Ọ̀rọ̀ Ààbò ṣe fi àánú hàn sí àwọn ẹlẹ́wọ̀n yìí [ìyẹn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà] torí pé wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn tó kù” ló mú kí wọ́n pinnu pé wọ́n á máa fi àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n sí ojú kan náà. Ọdún 1998 ni orílẹ̀-èdè Gíríìsì jáwọ́ nínú fífi àwọn Ẹlẹ́rìí tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun sẹ́wọ̀n.

Ìjọba ilẹ̀ South Korea náà ti fàánú hàn sáwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé wọn ò fẹ́ ṣe ohun tó ta ko ohun tí wọ́n gbà gbọ́, * wọ́n ti ya ọ̀pọ̀ nínú wọn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù. Ọ̀pọ̀ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pọ̀ jù ló ti ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì ti mú kó rọrùn fáwọn yìí láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn fẹ́ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó wà ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Gunsan ń sọ àǹfààní tí wọ́n ti rí bí wọ́n ṣe yà wọ́n sọ́tọ̀, ó ní: “Wọn ò lè kó àwọn ìwàkiwà bíi ìṣekúṣe àti ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ ràn wá mọ́ báyìí. Àwa àti àwọn arákùnrin wa láǹfààní láti jọ sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró látinú Bíbélì.”

Ìjọba ò tíì fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lómìnira láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn bá fẹ́. A gbóríyìn fún ìjọba ilẹ̀ South Korea fún ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé lẹ́nu àìpẹ́ yìí láti ya àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn tó kù, àmọ́ wọn ò tíì ṣe ohun táwọn orílẹ̀-èdè míì ti ṣe tipẹ́tipẹ́ láti yanjú ọ̀rọ̀ yìí. Bí àpẹẹrẹ, látọdún 1997 ni orílẹ̀-èdè Gíríìsì ti ṣètò pé kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa ṣiṣẹ́ àṣesìnlú. Orílẹ̀-èdè Jámánì náà gbà tẹ́lẹ̀ pé kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa ṣiṣẹ́ àṣesìnlú, àmọ́ wọ́n tiẹ̀ ti wá fún wọn lómìnira pátápátá látọdún 2011. Lọ́dún 2000, orílẹ̀-èdè Taiwan náà ṣòfin tó fàyè gba àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun láti máa ṣiṣẹ́ àṣesìnlú.

Àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn lórílẹ̀-èdè South Korea ń retí pé ìjọba orílẹ̀-èdè àwọn máa ṣe ohun tí ìjọba àpapọ̀ sọ nípa ẹ̀tọ́ téèyàn ní láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́.

^ ìpínrọ̀ 9 Òfin tí ìjọba àpapọ̀ ṣe fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn kárí ayé lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà láyè, ó sì di dandan kí ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea tẹ̀ lé òfin yìí. Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ìwà Ìrẹ́jẹ tí Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Ń Hù Kò Tẹ́ Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Lọ́rùn.”

‘Wọn ò lè kó ìwàkiwà ràn wá mọ́ báyìí, àwa àtàwọn ará wa sì láǹfààní láti jọ máa sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró’