Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

South Korea

 

2018-06-19

SOUTH KOREA

Àwọn Ilé Ẹjọ́ ní South Korea Túbọ̀ Ń Wá Ojútùú Sọ́rọ̀ Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Dípò káwọn adájọ́ ní South Korea máa rán àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun lọ sẹ́wọ̀n, ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń wá àfidípò iṣẹ́ ológun fún wọn.

2018-06-19

SOUTH KOREA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní South Korea Pàrọwà sí Ààrẹ Pé Kó Yanjú Ọ̀rọ̀ Àwọn Tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń dúró de ìpinnu táwọn aláṣẹ máa ṣe lẹ́yìn tí wọ́n bá yiiri òfin tí ìjọba ti ń tẹ̀ lé látọdún yìí wá wò, èyí tó dá lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

2018-01-16

SOUTH KOREA

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Sọ Pé Ó Yẹ Kí Ìjọba South Korea Bọ̀wọ̀ fún Ẹ̀tọ́ Àwọn Tí Kò Fẹ́ Wọṣẹ́ Ológun

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilé ẹjọ́ kò tíì sọ ìpinnu ìjọba South Korea lórí ọ̀rọ̀ àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà láyè láti wọṣẹ́ ológun, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ ló sọ èrò wọn lórí ọ̀rọ̀ yìí.

2017-04-07

SOUTH KOREA

Ìjọba South Korea Ń Fìyà tí Kò Tọ́ Jẹ Dong-hyuk Shin

Wọ́n ń fìyà tí kò tọ́ jẹ Ọ̀gbẹ́ni Shin torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ológun tí wọ́n pè é fún, ìyẹn sì fi hàn pé wọ́n ń fi òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn dù ú.

2017-07-26

SOUTH KOREA

Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Rọ Ìjọba Pé Kí Wọ́n Má Ṣe Fi Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn Du Aráàlú

Àjọ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lórílẹ̀-èdè South Korea rọ ìjọba pé kí wọ́n má fi ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní lábẹ́ òfin dù wọ́n, tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

2017-03-22

SOUTH KOREA

“Ìpinnu Tó Dáa Jù tí Ilé Ẹjọ́ Ṣe Lọ́dún Yìí”

Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ní Gwangju dá àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́ta tó kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun láre. Àwọn ará South Korea sì ń retí ìpinnu tí ilé ẹjọ́ tó ga jù lórílẹ̀-èdè náà máa ṣe lórí ọ̀rọ̀ tó ti wà nílẹ̀.

2017-01-19

SOUTH KOREA

Ilé Ẹjọ́ Ìjọba ti Ilẹ̀ South Korea Máa Tó Ṣe Ìpinnu Ńlá Kan

Tí Ilé Ẹjọ́ náà bá ṣe ìpinnu tó gbe àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, kò ní sẹ́ni tó máa fi ẹ̀tọ́ òmìnira ẹ̀rí ọkàn àti òmìnira ẹ̀sìn du gbogbo ọmọ ilẹ̀ South Korea mọ́.

2016-10-06

SOUTH KOREA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Míì Tó Wà Lẹ́wọ̀n Lórílẹ̀-èdè South Korea Fẹjọ́ Sùn

Ìjọba ilẹ̀ South Korea ṣì ń fìyà jẹ àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí wọ́n ṣì ń tì wọ́n mọ́lé bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lómìnira ẹ̀sìn àti ẹ̀rí ọkàn.

2016-10-06

SOUTH KOREA

Ṣé Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Máa Fàyè Gba Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn?

Ilé ẹjọ́ ti kọ́kọ́ dá Ọ̀gbẹ́ni Seon-hyeok Kim láre torí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó ṣiṣẹ́ ológun. Kí ló wá dé tí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn fi fagi lé ẹjọ́ náà tí wọ́n sì dá a lẹ́bi?

2016-05-04

SOUTH KOREA

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Lábẹ́ Ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Rọ Ìjọba Orílẹ̀-èdè South Korea Pé Kí Wọ́n Fọwọ́ sí Ẹ̀tọ́ Láti Kọ Ohun tí Ẹ̀rí Ọkàn Ẹni Kò Gbà Láyè

Kárí ayé làwọn èèyàn ti ń retí ohun tí ìjọba máa ṣe ní báyìí tí Ìgbìmọ̀ ti sọ pé kí wọ́n tẹ̀ lé àdéhùn International Covenant on Civil and Political Rights.

2016-05-19

SOUTH KOREA

Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Ya Ọgọ́rọ̀ọ̀rún Àwọn tí Ẹ̀rí Ọkàn Ò Jẹ́ Kí Wọ́n Ṣiṣẹ́ Ológun Sọ́tọ̀ Kúrò Lára Àwọn Ọ̀daràn

Ìjọba orílẹ̀-èdè South Korea ti mú kí nǹkan rọrùn díẹ̀ fún ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun.

2016-05-19

SOUTH KOREA

Ìwà Ìrẹ́jẹ tí Ìjọba Ilẹ̀ South Korea Ń Hù Kò Tẹ́ Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Lọ́rùn

Ìwé kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé jáde ṣàlàyé ìwà ìrẹ́jẹ tó mú kí wọ́n fí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọ̀dọ́kùnrin sẹ́wọ̀n torí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun, bẹ́ẹ̀ ẹ̀rí ọkàn wọn ni kò jẹ́ kí wọ́n ṣe é.

2016-05-04

SOUTH KOREA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Àjọyọ̀ Ọgọ́rùn-ún Ọdún ní Korea

SEOUL, Korea—Oṣù pàtàkì ni November ọdún 2012 jẹ́ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ní orílẹ̀-èdè South Korea, torí oṣù náà ló pé ọgọ́rùn-ún ọdún tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè náà.