JULY 26, 2019
SPAIN
Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! ti Ọdún 2019 Tí A Ṣe Ní Madrid Lórílẹ̀-èdè Spain
Ọjọ́ Àpéjọ: July 19-21, 2019
Ibi Àpéjọ: Pápá Ìṣeré Wanda Metropolitano nílùú Madrid lórílẹ̀ èdè Spain
Àwọn Èdè Tí A Lò Fún Ìtòlẹ́sẹẹsẹ: Gẹ̀ẹ́sì, Sípáníìṣì, Èdè Adití Lọ́nà Ti Sípáníìṣì
Iye Àwọn Tó Wá: Ẹgbẹ̀rún méjìléláàdọ́ta, ọgọ́rùn-ún márùn-un àti mẹ́rìndínlógún (52,516)
Iye Àwọn Tó Ṣe Ìrìbọmi: Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (434)
Iye Àwọn Tó Wá Láti Orílẹ̀-Èdè Míì: Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (6,300)
Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tí Àlejò Ti Wá: Albania, Argentina, Bulgaria, Kánádà, Amẹ́ríkà Àárín, Dominican Republic, Gánà, Hungary, Kòríà, Netherlands, Peru, Slovenia, Taiwan, Tọ́kì àti Amẹ́ríkà
Ìrírí Tó Ṣẹlẹ̀ Lágbègbè Náà: César López, tó jẹ́ olùdarí òtẹ́ẹ̀lì tàwọn àlejò dé sí sọ pé: “Ìrírí àrà ọ̀tọ̀ lèyí jẹ́ fún wa. Ọ̀kan lára àwọn nǹkan tàwọn òṣìṣẹ́ wa ò lè ṣe kí wọ́n má sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ ni irú ẹni tàwọn àlejò tó wá síbi ayẹyẹ yìí jẹ́. Wọ́n ń rẹ́rìn-ín músẹ́, wọ́n nìwà ọmọlúàbí, wọ́n sì ṣeé sún mọ́. Mo gbà pé àwọn àlejò yìí ti kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ nípa àkòrí àpéjọ yín, ìyẹn “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé” kí wọ́n tó wá síbí. Gbogbo àwọn tó dé sí òtẹ́ẹ̀lì wa ni wọ́n fìfẹ́ hàn sí wa. Inú wa máa dùn láti rí àwọn àlejò yín nígbà míì.”
Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń fi ọ̀yàyà kí àwọn àlejò tó ń dé sí ibùdókọ̀ òfúrufú Adolfo Suárez Madrid-Barajas káàbọ̀
Arábìnrin kan àti àlejò tó wá sì àpéjọ náà ń wàásù láti fi ìwé ìkésíni pé àwọn èèyàn wá sí àpéjọ náà
Àwọn àlejò ń rọ́ lọ sí ibi àpéjọ náà fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ òwúrọ̀
Àwọn àlejò tó wà láti orílẹ̀ èdè míì ń juwọ́ pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ ní òpin ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ Friday
Àwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì kan na fóònù wọn sókè, wọ́n wà ní ọ̀kan lára àwọn ibi tí wọ́n ṣe àtagbà àpéjọ náà sí , wọ́n sì ti wa Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tí a tún ṣe lédè Sípáníìṣì sórí ẹ̀. A mú Bíbélì yìí jáde lẹ́ẹ̀kan náà ní Madrid àti ibi mọ́kànlá (11) míì yíká orílẹ̀-èdè Spain lọ́jọ́ Friday
Ọ̀kan lára ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (434) arákùnrin àti arábìnrin tó ṣe ìrìbọmi ń rẹ́rìn lẹ́yìn ìrìbọmi
Àwọn àlejò tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ń juwọ́ sí àwùjọ láti orí pápá lọ́jọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ náà
Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń fi tayọ̀tayọ̀ pàtẹ́wọ́ nígbà tí àpéjọ náà ń lọ lọ́wọ́
Arákùnrin Gerrit Lösch, tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń bọ ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún lọ́wọ́ lẹ́yìn àpéjọ náà
Àwọn arábìnrin tó wọ aṣọ aláwọ̀ mèremère ń jó ijó ìbílẹ̀ Spain níbi àpèjẹ tí wọ́n ṣe nírọ̀lẹ́