Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 27, 2020
SPAIN

Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Gba Lẹ́tà Ìdúpẹ́ Látọ̀dọ̀ Nọ́ọ̀sì Kan

Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kan Gba Lẹ́tà Ìdúpẹ́ Látọ̀dọ̀ Nọ́ọ̀sì Kan

Lásìkò àrùn corona tó gbòde yìí, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa máa ń kọ lẹ́tà sí àwọn aládùúgbò wọn, kí wọ́n lè tù wọ́n nínú. Arákùnrin Josué Laporta àti ìyàwó ẹ̀ Vanesa kọ lẹ́tà ìtùnú sí àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìwòsàn kan tó wà nílùú Barcelona, lórílẹ̀-èdè Spain, wọ́n sì tún kọ ọ́ sáwọn tó ní àrùn corona nílé ìwòsàn náà. Nọ́ọ̀sì kan fèsì lẹ́tà tí tọkọtaya náà kọ, nọ́ọ̀sì náà sì gbà pé ká gbé e jáde lẹ́yìn tá a ṣàtúnṣe díẹ̀ sí i, kí ọ̀rọ̀ ẹ̀ lè ṣe kedere. Ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà náà ló wà nísàlẹ̀ yìí. *

Nọ́ọ̀sì ni mí . . . , torí ìyá àgbà, ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún (97ni mo ṣe ń kọ lẹ́tà yìí [a ti yọ orúkọ ìyá náà kúrò]. Àárọ̀ yìí la ka lẹ́tà yín fún wọn. Àwa òṣìṣẹ́ la máa fún àwọn aláìsàn ní lẹ́tà táwọn èèyàn bá kọ sí wọn, ẹni tí lẹ́tà bá sì ti bọ́ sí lọ́wọ́ ló máa mú un lọ, àmọ́ mo mọ̀ pé lẹ́tà yín ò kàn ṣàdédé bọ́ sọ́wọ́ mi. Ó kéré tán, ẹni méjì, ìyẹn èmi àti [ìyá yìí], ni lẹ́tà yín . . . jẹ́ kó ṣe kedere sí pé ìrètí ṣì wà. Mo mọ̀ pé kò ní pẹ́ mọ́ tí ìyá yìí máa fi kú, ó sì sọ fún mi pé òun ò fẹ́ fi ayé yìí sílẹ̀ láìjẹ́ pé òun bi ìwọ, Josué, ní ìbéèrè yìí, pé: “Bó ṣe jẹ́ pé ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún (97ni mí, ṣé mo ṣì lè jàǹfààní látinú àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì?”

Mo yọ̀ǹda ìṣẹ́jú mẹ́wàá nínú àkókò mi láàárọ̀ yìí kí n lè ka díẹ̀ lára àwọn ohun tó wà lórí ìkànnì tẹ́ ẹ tọ́ka sí fún [ìyá]. Ohun tí ìyá gbọ́ wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an, ó sì hàn lójú wọn, inú wọn dùn, ara sì tù wọ́n, kódà ara ò tù wọ́n báyìí rí. Lẹ́yìn náà, a wo fídíò “Kí Nìdí Tí Jésù Fi Kú?

Mo tún ka ìwé ìròyìn [“Jí!”] tó sọ nípa béèyàn ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ó sì jẹ́ kí n lè fara da àkókó tí nǹkan ò rọrùn yìí. Ẹ̀yin náà gbà pé nǹkan ò rọrùn, àbí mo parọ́?

Àwọn oníṣègùn wa níbí ò ní àwọn afìṣemọ̀rònú téèyàn lè fọ̀rọ̀ lọ̀, àmọ́ kò sígbà téèyàn ò lè lọ sórí ìkànnì tẹ́ ẹ tọ́ka wa sí, àwọn ìsọfúnni tó wà níbẹ̀ sì máa ń jẹ́ kéèyàn ronú jinlẹ̀. Tí gbogbo wàhálà yìí bá kúrò nílẹ̀, á wù mí kí n kẹ́kọ̀ọ́ sí i, mo sì mọ̀ pé ẹ ò ní jìnnà sí mi kẹ́ ẹ lè kọ́ mi lóhun tó yẹ kí n mọ̀, kó sì lè dá mi lójú pé ayé yìí ṣì máa dáa. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run gan-an pé lẹ́tà yín débí lọ́jọ́ yẹn, ó tún wá jẹ́ ọjọ́ tí mo wà lẹ́nu iṣẹ́, tó sì tún jẹ́ pé èmi gan-an ni mo mú lẹ́tà náà lọ sí yàrá tí [ìyá àgbà] náà wà.

Ṣé àlàáfíà ni ẹ̀yin àti ìdílé yín wà? Mo mọ̀ pé ìrètí tẹ́ ẹ ní á jẹ́ kẹ́ ẹ lè máa fara da àkókò yìí ju gbogbo àwa yòókù lọ. Ẹ ṣeun àkókò tẹ́ ẹ yọ̀ǹda láti kọ lẹ́tà sáwọn èèyàn bí èmi àti [ìyá àgbà]. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò mọra rí, ẹ ti fi ẹ̀rín sí wa lẹ́nu, irú ẹ̀rín tá ò rín láti ọ̀sẹ̀ mẹ́fà sẹ́yìn.

Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín látọkàn mi wá.

Àwọn ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ bí èyí máa ń fún wa níṣìírí ká lè máa tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa lákòókò àjàkálẹ̀ àrùn yìí. Àdúrà wa ni pé kí àwọn ọ̀rọ̀ tá a máa lò lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa jẹ́ èyí tó máa tu àwọn èèyàn nínú.​—Òwe 15:23.

^ ìpínrọ̀ 2 Èdè Spanish ni nọ́ọ̀sì náà fi kọ lẹ́tà yìí.