Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

JULY 8, 2016
SRI LANKA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣèrànwọ́ Lẹ́yìn Omíyalé Tó Ṣẹlẹ̀ ní Siri Láńkà

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣèrànwọ́ Lẹ́yìn Omíyalé Tó Ṣẹlẹ̀ ní Siri Láńkà

Àwọn Ẹlẹ́rìí ń kó ohun tí wọ́n fẹ́ lọ fi ṣèrànwọ́ sínú mọ́tò.

ÌLÚ COLOMBO, ní Siri Láńkà—Pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ ya wọ àwọn abúlé tó wà nílùú Aranayaka láti àwọn òkè tó wà láàárín ìlú náà. Nǹkan bíi máìlì méjìlélọ́gọ́ta [62] ni ìlú yìí sí ìlú Colombo, olú-ìlú Siri Láńkà. Ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún [100] èèyàn ni pọ̀tọ̀pọ́tọ̀ náà pa, ó sì ba ohun ìní àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ààbọ̀ [350,000] jẹ́. May 15 ni òjò ńlá tó fa omíyalé yìí bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀ lágbègbè yẹn. Nígbà kan tó tiẹ̀ fi odindi ọjọ́ kan rọ̀ nílùú Kilinochchi, omi òjò náà fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ẹsẹ̀ bàtà kan ààbọ̀ sílẹ̀. Àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Siri Láńkà sọ pé lẹ́yìn àkúnya omi tó wáyé lórílẹ̀-èdè náà lọ́dún 2004, kò tíì sí ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú tó èyí tó ṣẹlẹ̀ nílùú Aranayaka yìí lórílẹ̀-èdè Siri Láńkà.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Siri Láńkà ti fi tó wa létí pé Ẹlẹ́rìí kankan ò bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó igba [200] ni ilé wọn bà jẹ́. Omi tó ga tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà bo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ìyẹn ilé ìjọsìn tó wà ní Kaduwela, nǹkan bíi máìlì mẹ́sàn-án sílùú Colombo.

Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Kotahena, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ń ṣètò omi inú ike, oúnjẹ, aṣọ àti oògùn tí wọ́n fẹ́ kó lọ fáwọn tí àjálù dé bá.

Àwọn Ẹlẹ́rìí yára ṣètò ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ nígbà àjálù kí wọ́n lè bójú tó àwọn tí àjálù dé bá, kí wọ́n pèsè ohun tí wọ́n nílò fún wọn, kí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tù wọ́n nínú. Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní Kotahena ni wọ́n kó omi mímu àti aṣọ sí, pẹ̀lú oògùn àtàwọn ohun tí wọ́n fi ń tọ́jú aláìsàn. Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé lágbègbè yẹn ló yọ̀ǹda ara wọn láti pín ohun táwọn ará wọn àtàwọn aládùúgbò nílò fún wọn.

Ọ̀gbẹ́ni Nidhu David, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Siri Láńkà sọ pé: “A ò dákẹ́ àdúrà lórí ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé tí ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé láìpẹ́ yìí ṣèpalára fún. Lẹ́sẹ̀ kan náà, à ń bá wọn tún ilé wọn tí omi bà jẹ́ ṣe, à ń pín oúnjẹ, a sì ń dá aṣọ jọ fún àwọn tí ò láṣọ. Báwọn ará wa ṣe ṣètìlẹyìn, tí wọ́n sì tún yọ̀ǹda ara wọn yìí dà bí omi tútù lásìkò ọ̀gbẹlẹ̀ fún àwọn tí àjálù yìí dé bá.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Oríléeṣẹ́: J. R. Brown, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, 1-718-560-5000

Siri Láńkà: Nidhu David, 94-11-2930-444