Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 11, 2017
TAIWAN

Ètò Iṣẹ́ Àṣesìnlú Yọrí sí Rere Lórílẹ̀-èdè Taiwan

Ètò Iṣẹ́ Àṣesìnlú Yọrí sí Rere Lórílẹ̀-èdè Taiwan

Lọ́dún 2000, ìjọba orílẹ̀-èdè Taiwan fọwọ́ sí i pé káwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun máa ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú ní àfidípò sí iṣẹ́ ológun, èyí á jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ojúṣe wọn láti ṣiṣẹ́ sin ìjọba láìṣe ohun tó máa ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn. Ètò tí ìjọba ṣe yìí ti jẹ́ kí àwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ráyè máa ṣiṣẹ́ sìnlú láwọn ilé ìwòsàn, ilé tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn arúgbó àti láwọn ibòmíì nílùú. Ètò yìí ti ṣe bẹbẹ, kódà, ó ṣàǹfààní ju bí ìjọba ṣe rò lọ. Àwọn aráàlú ń jadùn ẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà làwọn tí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun ń gbádùn ẹ̀ torí bí ìjọba ò ṣe fi wọ́n sẹ́wọ̀n mọ́ torí pé wọn ò wọṣẹ́ ológun.

Nínú fídíò yìí, ẹ máa rí bí ètò iṣẹ́ àṣesìnlú ṣe bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Taiwan, ẹ̀ẹ́ rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tí àwọn tí kò fara mọ́ ètò yìí sábà máa ń béèrè, ẹ̀ẹ́ sì gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn tọ́rọ̀ kàn fúnra wọn. Ọ̀gbẹ́ni Kou-Enn Lin, tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Àjọ Tó Ń Fani Wọṣẹ́ Ológun sọ pé: “Á wù mí tí àwọn ìjọba orílẹ̀-èdè míi bá fi tiwa ṣe àríkọ́gbọ́n.”