Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 20, 2019
THAILAND

A Mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun Jáde Lédè Laotian

A Mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun Jáde Lédè Laotian

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Laotian níbi àpéjọ agbègbè tí a ṣe ní Nong Khai, lórílẹ̀-èdè Thailand, ní August 16, 2019. Arákùnrin Plakorn Pestanyee tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Thailand, ló mú Bíbélì náà jáde lọ́jọ́ àkọ́kọ́ àpéjọ náà.

Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni-mẹ́ta tó túmọ̀ Bíbélì náà lo ọdún kan ààbọ̀ lórí iṣẹ́ náà. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Ní báyìí, a ti ní ìtumọ̀ Bíbélì kan tó ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì lọ́nà tí àwọn tó ń sọ èdè Laotian gbà ń sọ̀rọ̀, síbẹ̀ ó gbé ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ jáde lọ́nà tó pé pérépéré, kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lè lóye ‘àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.’ ”​—Jóòbù 11:7.

Bíbélì tuntun yìí ní àwọn ohun èlò ìwádìí bí atọ́ka, tó máa ran àwọn tó ń kà á lọ́wọ́ láti tètè rí àwọn ẹsẹ Bíbélì àti àlàyé ọ̀rọ̀ tó ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì. Atúmọ̀ èdè míì tóun náà ṣe nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ náà sọ pé: “Tá a bá fi Bíbélì yìí kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì á lóye àwọn koko pàtàkì lọ́nà tó rọrùn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, á sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn, èyí á sì jẹ́ kí wọ́n ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.”

Ó dá wa lójú pé Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun yìí á ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó ń sọ èdè Lao lọ́wọ́ láti kí wọ́n lè “kúnjú ìwọ̀n dáadáa, kí wọ́n sì gbára dì pátápátá fún gbogbo iṣẹ́ rere.”​—2 Tímótì 3:​16, 17.