DECEMBER 2, 2019
TOGO
Àkúnya Omi Wáyé Lórílẹ̀-Èdè Tógò
Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá tó wáyé lórílẹ̀-èdè Tógò ní àsìkò òjò ọdún 2019 fa àkúnya omi ní ibi púpọ̀ láwọn ìgbèríko ìlú Lome, lórílẹ̀-èdè Tógò. Àwọn akéde ọgọ́rùn-ún méjì ó lé mẹ́tàdínlọ́gọ́ta (257) tó wà ní ìjọ méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló fara gbá nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ẹ̀ka ọ́fíìsì tó ń bójú tó orílẹ̀-èdè náà ti ń pèsè ìrànwọ́ fún àwọn akéde yìí.
Láwọn ibì kan tí àkúnya omi náà ti ṣẹlẹ̀, omi náà fẹ́ẹ̀ mu èèyàn dé ìbàdí, èyí mú kó pọndandan kí àwọn ará tó jẹ́ mọ́kànléláàádọ́ta (51) sá kúrò nílé. Àwọn akéde tó wà nítòsí ti gba àwọn ará yìí sílé, wọ́n sì ń bójú tó wọn.
Àgbàrá òjò ti ba díẹ̀ lára àwọn omi tó ṣeé lò ní agbègbè yẹn jẹ́. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Benin tó ń bójú tó iṣẹ́ wa ní Tógò ti ṣètò pé kí alábòójútó àyíká àtàwọn alàgbà pín àwọn nǹkan táwọn ará wa lè lò fún wọn. Lára ẹ̀ ni oògùn tó ń pa kòkòrò inú omi, kẹ́míkà apakòkòrò àti kẹ́míkà tí wọ́n fi ń sọ aṣọ di funfun tí wọ́n ń pè ní bleach.
A gbàdúrà pé kí Jèhófà bù kún àwọn ará wa ní Tógò bí wọ́n ṣe ń fi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ hàn síra wọn.—Jòhánù 13:34, 35.