Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Láti apá òsì sí apá ọ̀tún: Arákùnrin Eldor àti Sanjarbek Saburov, tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò

AUGUST 7, 2020
TURKMENISTAN

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Turkmen Rán Arákùnrin Eldor àti Sanjarbek Saburov Lọ sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Méjì

Ilé Ẹjọ́ Kan ní Turkmen Rán Arákùnrin Eldor àti Sanjarbek Saburov Lọ sí Ẹ̀wọ̀n Ọdún Méjì

Ní August 6, 2020, ilé ẹjọ́ kan ní Turkmen rán Arákùnrin Eldor àti Sanjarbek Saburov lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wọ́n, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún (21) ni àbúrò, ọmọ ọdún márùndínlọ́gbọ̀n (25) sì ni èyí ẹ̀gbọ́n. Àwọn arákùnrin náà fẹ́ pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àmọ́ ilé ẹjọ́ ò fọwọ́ sí i. Ìgbà kejì rèé tí ilé ẹjọ́ máa dá àwọn méjèèjì lẹ́bi torí wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun.

Lọ́dún 2016, Arákùnrin Sanjarbek Saburov fara balẹ̀ ṣàlàyé fáwọn aláṣẹ pé òun ò ní lè wọṣẹ́ ológun. Àmọ́ wọ́n dá a lẹ́bi, wọ́n sì fi í sí àtìmọ́lé ọdún méjì.

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Eldor tó jẹ́ àbúrò sọ pé òun náà ò ní wọṣẹ́ ológun. Wọ́n rán an lọ síbi táá ti máa ṣe iṣẹ́ àṣekára fún ọdún méjì, ìjọba sì ń gba ìdá márùn-ún nínú owó oṣù tí wọ́n ń san fún un níbẹ̀.

Bí òfin ilẹ̀ Turkmen ṣe sọ, tẹ́nì kan bá ń sọ pé òun ò ní wọṣẹ́ ológun lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ pè é lẹ́jọ́, àwọn aláṣẹ lè pe onítọ̀hún lẹ́jọ́ lẹ́ẹ̀kejì. Nígbà tó di April 2020, ọ́fíìsì àwọn ológun tún pe àwọn arákùnrin yìí pé kí wọ́n wá wọṣẹ́ ológún. Àmọ́ àwọn méjèèjì sọ pé àwọn ò ní ṣiṣẹ́ ológún. Bí wọ́n ṣe pè wọ́n lẹ́jọ́ nìyẹn, tí wọ́n fi wá dèrò ẹ̀wọ̀n báyìí.

Ìbànújẹ́ ńlá ló bá òbí àwọn arákùnrin yìí torí ohun tó ṣẹlẹ̀, àtirí owó gbọ́ bùkátà sì wá dìṣòro fún wọn. Bàbá wọn níṣòro ẹ̀yìn dídùn, torí náà kò lè fi bẹ́ẹ̀ ṣiṣẹ́. Àwọn ọmọ ẹ̀ yìí ló ń ṣe èyí tó pọ̀ jù, torí wọ́n ń dáko òwú. Àmọ́ ní báyìí tí wọ́n ti dèrò ẹ̀wọ̀n, gbogbo ìrànwọ́ táwọn ọmọ wọn ń ṣe ti dáwọ́ dúró. Àwọn ọmọ yìí ló yẹ kí wọ́n máa tọ́jú àwọn òbí wọn, àmọ́ àwọn òbí gangan ló wá dẹni tó ń tọ́jú àwọn ọmọ tó wà lẹ́wọ̀n báyìí.

Ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ò fọwọ́ sí ètò iṣẹ́ àṣesìnlú. Torí náà, tí ọ̀dọ́kùnrin èyíkéyìí bá kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kó ṣe bẹ́ẹ̀, ó lè fi ẹ̀wọ̀n ọdún kan sí ọdún mẹ́rin gbára. Ní báyìí, àwọn ọ̀dọ́kùnrin mẹ́wàá tó fi mọ́ àwọn ọ̀dọ́ méjì táá sọ̀rọ̀ wọn yìí ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan, torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣé ológun.

A mọ̀ pé Jèhófà máa bù kún àwọn arákùnrin wa ní Turkmenistan torí pé wọ́n fìgboyà ṣe ohun tó tọ́. Àdúrà wa ni pé kí gbogbo wọn máa rántí ìlérí tí Jèhófà ṣe fún Ọba Ásà pé: “Ní tiyín, ẹ jẹ́ alágbára, ẹ má sì jẹ́ kí ìrẹ̀wẹ̀sì bá yín, nítorí pé èrè wà fún iṣẹ́ yín.”​—2 Kíróníkà 15:7.