Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Serdar Dovletov ní June 2019

DECEMBER 9, 2019
TURKMENISTAN

Ilé Ẹjọ́ Orílẹ̀-Èdè Turkmenistan Fi Arákùnrin Dovletov Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ta Nítorí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ̀ Kò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun

Ilé Ẹjọ́ Orílẹ̀-Èdè Turkmenistan Fi Arákùnrin Dovletov Sẹ́wọ̀n Ọdún Mẹ́ta Nítorí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ̀ Kò Jẹ́ Kó Ṣiṣẹ́ Ológun

Ní November 12, 2019, Ilé ẹjọ́ kan ní orílẹ̀-èdè Turkmenistan dá Arákùnrin Serdar Dovletov lẹ́bi, ó sì fi sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta. Ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n (26) ni Arákùnrin Dovletov. Arákùnrin Dovletov wà lára àwọn arákùnrin mẹ́wàá ní orílẹ̀-èdè náà tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣiṣẹ́ ológun. Àwọn méje ni wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní 2019, wọ́n ti fi àwọn mẹ́ta yòókù sẹ́wọ̀n ní 2018. Àkókò tí wọ́n ní kí wọ́n lò lẹ́wọ̀n jẹ́ láàárín ọdún kan sí mẹ́rin.

Ìlú Baýramaly ni Arákùnrin Dovletov ti wá, ní agbègbè Mary tó wà ní apá gúúsù ìlà oòrùn Turkmenistan. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Surya ìyàwó ẹ̀ àti Sonya màmá rẹ̀.

November 11, 2019 ni ìgbẹ́jọ́ Arákùnrin Dovletov bẹ̀rẹ̀. Arákùnrin Dovletov sọ fún ilé ẹjọ́ náà pé ìsìn òun ló mú kí ẹ̀rí ọkàn òun kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Ní àfikún, àwọn dókítà mẹ́ta ló jẹ́rìí pé Arákùnrin Dovletov ní ọgbẹ́ inú ọlọ́jọ́ pípẹ́, ìyẹn náà sì wà lára ìdí tó fi yẹ kí wọ́n yọ̀ǹda ẹ̀ láti má ṣiṣẹ́ ológun.

Láìka àwọn ẹ̀rí yìí sí, adájọ́ náà sọ pé Arákùnrin Dovletov jẹ̀bi fífi “ọgbọ́n jìbìtì” sá fún iṣẹ́ ológun, ó sì sọ pé kí wọ́n fi sí àhámọ́. Láìpẹ́, ó máa dara pọ̀ mọ́ àwọn arákùnrin mẹ́sàn-an tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Seydi nínú aṣálẹ̀ kan lágbègbè Lebap. Arákùnrin Dovletov máa pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ìdájọ́ náà.

Bí àwọn arákùnrin wa ní Turkmenistan ṣe ń fara da ìwà ìrẹ́jẹ lórílẹ̀-èdè wọn, à ń gbàdúrà fún wọn pẹ̀lú ìgbàgbọ́ kíkún nínú ìlérí Jèhófà pé á tì wọ́n lẹ́yìn bí wọ́n ṣe ń fi ìgboyà di ìṣòtítọ́ wọn mú.​—Sáàmù 37:18, 24.