Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 3, 2020
TURKMENISTAN

Wọ́n Tú Arákùnrin Petrosov Sílẹ̀ ní Turkmenistan Lẹ́yìn Tó Lo Ọdún Kan Lẹ́wọ̀n

Wọ́n Tú Arákùnrin Petrosov Sílẹ̀ ní Turkmenistan Lẹ́yìn Tó Lo Ọdún Kan Lẹ́wọ̀n

Orílẹ̀-èdè Turkmenistan ni Arákùnrin David Petrosov ń gbé, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́ ṣì ni, síbẹ̀ ó ti kojú ìṣòro tó dán ìgbàgbọ́ ẹ̀ wò, ó ti lo ọdún kan lẹ́wọ̀n torí pé kò gbà láti wọ iṣẹ́ ológun. Wọ́n tú u sílẹ̀ ní September 30, 2020.

Arákùnrin Petrosov sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà ni inú mi kì í dùn nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n. Àmọ́ àwọn nǹkan tí mò ń kà nínú Bíbélì máa ń tù mí nínú. Mo mọ̀ pé Jèhófà mọ bí nǹkan ṣe rí lára mi, ó sì ṣe tán láti mára tù mí, torí náà ó máa ń yá mi lára láti gbàdúrà sí i. Oríṣiríṣi ẹsẹ Bíbélì ló máa ń ràn mí lọ́wọ́ láwọn ipò tó yàtọ̀ síra, àmọ́ èyí tí mo máa ń rántí jù ni Fílípì 4:13.”

Ìlú Ashgabat tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Turkmenistan ni wọ́n bí Arákùnrin Petrosov sí. Bó ṣe ń dàgbà, ó kọ́ bí wọ́n ṣe ń ta gìtá. Ó fẹ́ràn kó máa ṣe orin fúnra ẹ̀, kó máa gbá bọ́ọ̀lù, kó máa gbafẹ́ lọ sáwọn òkè, kó sì máa lúwẹ̀ẹ́.

Ọmọ kíláàsì ẹ̀ kan ló kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2019. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìkankan nínú àwọn mọ̀lẹ́bí David tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, síbẹ̀ wọn ò fojú kéré èrò ẹ̀ lórí ohun tó gbà gbọ́.

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí David ṣèrìbọmi ni wọ́n gbé e lọ sílé ẹjọ́ torí pé ó kọ̀ láti wọ iṣẹ́ ológun. Lórílẹ̀-èdè Turkmenistan, wọn ò ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì fáwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà wọ́n láyè láti ṣe iṣẹ́ ológun. Torí náà, ilé ẹjọ́ ní kí wọ́n fi David sẹ́wọ̀n ọdún kan.

Jèhófà ran Arákùnrin Petrosov lọ́wọ́ ní gbogbo àsìkò tó fi wà lẹ́wọ̀n. Arákùnrin Petrosov sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí mọ́mì mi bá wá kí mi lẹ́wọ̀n ni wọ́n máa ń jíṣẹ́ àwọn ará. Wọ́n jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn ará ò dákẹ́ àdúrà lórí mi. Ìyẹn sì ń múnú mi dùn gan-an.”

David mọ̀ pé òfin orílẹ̀-èdè Turkmenistan fàyè gbà á pé kí wọ́n ní kóun wá wọṣẹ́ ológun lẹ́ẹ̀kan si. Tí ò bá sì gbà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n dá a lẹ́bi, kí wọ́n fi sẹ́wọ̀n, kí wọ́n sì ní kó lò ju ọdún kan lọ.

David sọ pé: “Ẹ̀yin náà mọ̀ pé kò sẹ́ni tínú ẹ̀ máa dùn láti lọ sẹ́wọ̀n, torí náà kò wù mí kí n pa dà sẹ́wọ̀n. Àmọ́, ẹ̀rù ò bà mí. Torí ó dá mi lójú pé Jèhófà àtàwọn ará nífẹ̀ẹ́ mi, mo sì ti túbọ̀ nígboyà bí mo ṣe ń kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run.”

Ó dá wa lójú pé Jèhófà á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ David túbọ̀ máa lágbára sí i, á sì máa fún un nígboyà. A tún ń gbàdúrà fáwọn arákùnrin wa mẹ́wàá tó ṣì wà lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan torí pé ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun. Ó dá wa lójú pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wọn, ó ń rántí wọn, kò sì ní fi wọ́n sílẹ̀.​—Sáàmù 69:33.