Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Arákùnrin Selim Taganov

NOVEMBER 24, 2020
TURKMENISTAN

Wọ́n Tú Arákùnrin Taganov Sílẹ̀ Lẹ́yìn Tó Lo Ọdún Kan Lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan

Wọ́n Tú Arákùnrin Taganov Sílẹ̀ Lẹ́yìn Tó Lo Ọdún Kan Lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan

Lẹ́yìn tí wọ́n tú Arákùnrin Selim Taganov sílẹ̀ lẹ́wọ̀n ní October 3, 2020, ó sọ pé: “Gbogbo ìgbà tí mo bá gbàdúrà sí Jèhófà ló máa ń ràn mí lọ́wọ́, ìyẹn sì jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀.” Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19) péré ni Selim, àmọ́ ó ti lo ọdún kan lẹ́wọ̀n torí pé ẹ̀rí ọkàn ẹ̀ ò gbà á láyè láti wọṣẹ́ ológun.

Ìlú Ashgabat, tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Turkmenistan ni wọ́n ti bí Selim. Nígbà tó wà ní kékeré, ó ń ṣe dáadáa níléèwé, ó sì fẹ́ràn kó máa kọrin. Ó máa ń ṣàkójọ orin, ó sì máa ń ta gìtá. Nígbà táwọn òbí Selim àtàwọn àbúrò ẹ̀ ń sọ irú ẹni tí Selim jẹ́, wọ́n ní onínúure àtèèyàn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ni, ó sì máa ń láyọ̀ nígbà gbogbo. Nígbà tí wọ́n ń dá ẹjọ́ Selim, agbejọ́rò tí ilé ẹjọ́ ní kó dúró fún Selim sọ pé: “Ọmọlúwàbí ni, kì í mu sìgá, kì í sì í mutí àmupara, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe tán nílé ẹ̀kọ́ girama ni. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n bà á láyé jẹ́ tẹ́ ẹ bá fi sẹ́wọ̀n.”

Ká sòótọ́, nǹkan ò rọrùn fún Selim lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Àmọ́, ó sọ pé: “Àjọṣe èmi àti Jèhófà ti lágbára sí i ní gbogbo àsìkò tí mo fi wà lẹ́wọ̀n. Mo máa ń ronú nípa àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ máa lóye wọn. Ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Bíbélì tó fún mi lókun ni Àìsáyà 41:10, 11.

“Nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ fi mí sátìmọ́lé kí wọ́n tó fi mí sẹ́wọ̀n, nǹkan nira fún mi gan-an torí mi ò rẹ́ni bá sọ̀rọ̀. Àmọ́, mo gbàdúrà sí Jèhófà pé kó ràn mí lọ́wọ́. Lẹ́yìn náà, àwọn ẹlẹ́wọ̀n àtàwọn ẹ̀ṣọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ ń halẹ̀ mọ́ mi wá bẹ̀rẹ̀ sí í ràn mí lọ́wọ́, wọ́n sì ń fún mi níṣìírí. Ìyẹn jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé Jèhófà ń tì mí lẹ́yìn.”

Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tún fún Selim lókun. Selim sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló máa ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí mi nígbà tí mo wà lẹ́wọ̀n, wọ́n sì máa ń kọ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí sínú lẹ́tà náà. Mo máa ń gbìyànjú láti há àwọn ọ̀rọ̀ yẹn sórí, màá wá máa sọ ọ́ léraléra. Ìyẹn máa ń fún mi lókun, ó sì máa ń tù mí nínú.”

Bó ṣe wà nínú ìwé òfin orílẹ̀-èdè Turkmenistan, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì wá mú Selim pé kó wọṣẹ́ ológun lẹ́ẹ̀kan sí i. Tí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, Selim mọ̀ pé wọ́n lè ní kóun lò ju ọdún kan lọ lẹ́wọ̀n. Síbẹ̀, ó sọ pé: “Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti fara da àtakò yìí, torí náà mi ò bẹ̀rù ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Jèhófà wà lẹ́yìn mi, torí náà ọkàn mi balẹ̀.”

Bó ṣe jẹ́ pé gbogbo wa la lè níṣòro lọ́jọ́ iwájú. Ohun tí Selim sọ lè ràn wá lọ́wọ́, ó ní: “Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ bára yín nírú ipò yìí lọ́jọ́ iwájú, ẹ máa rántí ohun tó wà nínú Àìsáyà 30:15 pé: ‘Ẹ máa lágbára tí ẹ bá fara balẹ̀, tí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé mi.’”