Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

TURKMENISTAN

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Turkmenistan

Àlàyé Ṣókí Nípa Orílẹ̀-èdè Turkmenistan

Láti nǹkan bí ọdún 1985 sí 1989 ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wà lórílẹ̀-èdè Turkmenistan. Kò pẹ́ tí orílẹ̀-èdè náà gbòmìnira lábẹ́ ìjọba Soviet Union ní October 1991 tí ìjọba fi bẹ̀rẹ̀ sí í fòfin de ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì mú kí nǹkan nira gan-an fún wọn.

Kò sórúkọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lábẹ́ òfin ní orílẹ̀-èdè Turkmenistan. Wọ́n ti lu àwọn Ẹlẹ́rìí kan nílùkulù, àwọn aláṣẹ tì wọ́n mọ́lé láìnídìí, wọ́n túlé wọn, wọ́n fi wọ́n sẹ́wọ̀n, wọ́n sì bu owó ìtanràn lé wọn torí pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Láwọn ìgbà míì, ṣe ni àwọn ọlọ́pàá máa ń lọ́ ẹ̀sùn mọ́ wọn lẹ́sẹ̀, ìyẹn sì sọ wọ́n dèrò ẹ̀wọ̀n. Bákan náà, torí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ò ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú, wọ́n máa ń pe àwọn ọ̀dọ́kùnrin lẹ́jọ́, wọ́n sì máa ń fìyà jẹ wọ́n torí pé ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ̀wé sí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè lórí ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n sì tún fi tó àwọn iléeṣẹ́ ìjọba míì lágbàáyé létí.

Ní October 2014, Ààrẹ orílẹ̀-èdè Turkmenistan dá àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́jọ tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n láìtọ́ sílẹ̀. Gbangba ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan fún ìgbésẹ̀ tó dáa tí wọ́n gbé yìí. Wọ́n ń retí pé ìjọba máa tún gbé àwọn ìgbésẹ̀ míì tó máa jẹ́ káwọn èèyàn lómìnira ẹ̀sìn.