MARCH 28, 2018
TURKMENISTAN
Orílẹ̀-Èdè Turkmenistan Gbójú Fo Òmìnira Láti Ṣe Ohun Tó Bá Ẹ̀rí Ọ̀kan Ẹni Mu
Ní January 2018, ìjọba fẹ̀sùn kan Arslan Begenjov àti Kerven Kakabayev pé wọ́n sá fún iṣẹ́ ológun, ó sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n ọdún kan. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn ọ̀dọ́kùnrin méjèèjì, wọ́n sì kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú míì dípò iṣẹ́ ológun, ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ta kú pé àwọn ọ̀dọ́kùnrin yìí lẹ́tọ̀ọ́ sọ pé àwọn ò lè ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò fẹ́, wọn ò sì ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì dípò iṣẹ́ ológun.
Wọ́n Mú Àwọn Ẹlẹ́rìí, Wọ́n Dá Wọn Lẹ́bi, Wọ́n sì Fi Wọ́n Sẹ́wọ̀n
Àwọn aláṣẹ mú Ọ̀gbẹ́ni Begenjov ní January 2, wọ́n sì tì í mọ́lé fúngbà díẹ̀ títí wọ́n á fi gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Ní January 17, ilé ẹjọ́ dá a lẹ́bi pé ó sá fún iṣẹ́ ológun, wọ́n sì fi í sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan. Ọ̀gbẹ́ni Begenjov ti pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn torí bí wọ́n ṣe jù ú sẹ́wọ̀n láìtọ́.
Wọ́n mú Ọ̀gbẹ́ni Kakabayev náà lóṣù January wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ọdún kan láìtọ́ ní January 29. Nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, ilé ẹjọ́ ò gbà kó mú àwọn ẹ̀rí tó gbe ẹjọ́ rẹ̀ wá, àwọn ẹ̀rí náà dá lé àwọn ìdájọ́ Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Ibi tọ́rọ̀ náà wá burú sí ni pé, bóyá ni ilé ẹjọ́ kankan máa fẹ́ gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí Ọ̀gbẹ́ni Kakabayev pè. Ìdí ni pé àwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n gbẹ́sẹ̀ lé ìwé tí agbẹjọ́rò rẹ̀ kọ láti fi pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn. Torí náà, kò sí bó ṣe lè buwọ́ lù ú bí òfin ṣe sọ pé kó ṣe láàárín ọjọ́ mẹ́wàá tí wọ́n dá ẹjọ́ rẹ̀.
Ìgbà kejì nìyí tí wọ́n máa fi ìyà jẹ Ọ̀gbẹ́ni Kakabayev torí pé ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò jẹ́ kó wọṣẹ́ ológun. Ní December 2014, àwọn aláṣẹ ní kó fi ọdún méjì ṣe iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n fi ń kọ́ ọ̀daràn lọ́gbọ́n, èyí máa gba pé kó máa san ìdá márùn-ún owó oṣù rẹ̀ sí àpò ìjọba ní gbogbo àkókò yẹn.
‘Kò Tíì Gbà Pé Èèyàn Ní Ẹ̀tọ́ Láti Kọ Ohun Tí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ̀ Ò Bá Gbà’
Ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan gbà pé òun kìí fi ẹ̀tọ́ àwọn ọmọ ilẹ̀ òun dù wọ́n. Síbẹ̀, kò tíì gbà pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọ́n ò gbà bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ní kó tẹ̀ lé ìlànà tó ti fìdí múlẹ̀ kárí ayé lórí ọ̀rọ̀ yìí.
Ní ọdún 2015 àti 2016, Ìgbìmọ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn dẹ́bi fún orílẹ̀-èdè Turkmenistan nínú ẹ̀sùn mẹ́wàá táwọn Ẹlẹ́rìí tó kọ̀ láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà fi kàn án. Nínú àwọn ìpinnu tí Ìgbìmọ̀ yìí ṣe, ó bá orílẹ̀-èdè Turkmenistan wí torí pé ó ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí, ó sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà. Ní April 2017, Ìgbìmọ̀ náà tún sọ bó ṣe jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún un tó pé orílẹ̀-èdè Turkmenistan “ò tíì gbà pé èèyàn ní ẹ̀tọ́ láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gbà tí wọ́n bá fi dandan lé e pé kó wá wọṣẹ́ ológun, kò sì dẹ́kun ṣíṣe inúnibíni àti fífi ìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí kò gbà ṣe iṣẹ́ ológun tíjọba fi dandan lé pé kí wọn ṣe.” Ó ní kí orílẹ̀-èdè Turkmenistan ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú míì fáwọn èèyàn, kó lè dẹ́kun bó ṣe ń bá àwọn tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò jẹ́ kí wọ́n wọṣẹ́ ológun ṣẹjọ́, kó sì dá àwọn tó ti jù sẹ́wọ̀n sílẹ̀ lórí pé wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun.
Láti ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn, ìjọba ti ṣe àwọn ìyípadà kan nínú bí wọ́n ṣe ń bójú tó ọ̀rọ̀ àwọn tó bá sọ pé àwọn ò ṣiṣẹ́ ológun torí ẹ̀rí ọkàn wọn. Láti December 2014, dípò kí wọ́n máa fi àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n kọ̀ láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà sẹ́wọ̀n, ṣe ni wọ́n kúkú ń gba ìdá márùn-ún nínú owó oṣù wọn fún ọdún kan tàbí méjì gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn (irú èyí tó ṣẹ̀lẹ̀ sí Ọ̀gbẹ́ni Kakabeyev lọ́dún 2014) tàbí, nínú àwọn ọ̀ràn kan, kí wọ́n pinnu ìyà tí wọ́n máa fi jẹ wọ́n. * Ní February 2015 orílẹ̀-èdè náà dá Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo tó kù lẹ́wọ̀n torí pé ó kọ̀ láti ṣe ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gbà sílẹ̀. Ó bani nínú jẹ́ pé, nínú ẹjọ́ Ọ̀gbẹ́ni Begenjov àti Ọ̀gbẹ́ni Kakabayev tó wáyé lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìjọba Turkmenistan tún pa dà hùwà rírorò bó tí máa ń ṣe tẹ́lẹ̀, dípò kó gbà pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti kọ ohun tí ẹ̀rí ọkàn wọn ò gbà.
Kí Ì Ṣe Torí Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Kọ̀ Láti Ṣe Ohun Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Ò Gbà Nìkan Ni Wọ́n Fi Ń Jù Wọ́n Sẹ́wọ̀n
Yàtọ̀ sí Ọ̀gbẹ́ni Begenjov àti Ọ̀gbẹ́ni Kakabayev táwọn aláṣẹ fi sẹ́wọ̀n lẹ́nu àìpẹ́ yìí, wọn ò tíì tú Bahram Hemdemov sílẹ̀ lẹ́wọ̀n torí pé ó lo ẹ̀tọ́ tó ní láti jọ́sìn. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, àmọ́ wọ́n mú un, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n ṣe ìpàdé ìsìn nínú ilé rẹ̀ tó wà ní ìlú Turkmenabad. Láti ọdún 2015 ni bàbá ọlọ́mọ-mẹ́rin yìí ti wà lẹ́wọ̀n, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni ààrẹ orílẹ̀-èdè Turkmenistan ti forí ji àwọn ẹlẹ́wọ̀n láàárín ọdún méjì tó kọjá. Ìjọba ti forí ji ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹlẹ́wọ̀n, àmọ́ kò kọbi ara sí gbogbo ẹ̀bẹ̀ tí wọ́n ń bẹ̀ ẹ́ pé kó tú Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov sílẹ̀.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí ìtura máa dé bá àwọn ará wọn lórílẹ̀-èdè Turkmenistan. Wọ́n retí pé orílẹ̀-èdè Turkmenistan máa tó fàyè gba ẹ̀tọ́ òmìnira ìjọsìn àti òmìnira ẹ̀rí ọkàn, tí á sì wá nǹkan ṣe sí ìwà ìrẹ́jẹ tó ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.
^ ìpínrọ̀ 10 Ìyà tí wọ́n fi ń jẹ ẹlòmíì ni pé wọ́n á fi sí abẹ́ àyẹ̀wò dípò kí wọ́n jù ú sẹ́wọ̀n.