Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

NOVEMBER 10, 2016
TURKMENISTAN

Ìjọba Ò Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan

Ìjọba Ò Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan

Ní October 25, 2016, ààrẹ orílẹ̀-èdè Turkmenistan dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ [1,500] sílẹ̀. Àmọ́ wọn ò dá Bahram Hemdemov àti Mansur Masharipov sílẹ̀. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn méjèèjì, ọgbà ẹ̀wọ̀n Seydi ni wọ́n sì fi wọ́n sí.

Àti March 2015 ni Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov ti wà látìmọ́lé torí pé wọ́n ń ṣe ìjọsìn nínú ilé rẹ̀ ní Turkmenabad, bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìrọwọ́rọsẹ̀ ní wọ́n ń ṣèjọsìn ọ̀hún. Ilé ẹjọ́ kan lórílẹ̀-èdè Turkmenistan wá rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin torí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án pé ó ń ṣe ìjọsìn tó ta ko òfin. June 2016 ni wọ́n mú Ọ̀gbẹ́ni Masharipov ní tiẹ̀ nílùú Ashgabad lórí ẹ̀sùn irọ́ tí wọ́n fi kàn án, wọ́n sì rán an lọ sí ẹ̀wọ̀n ọdún kan. Ó dun àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà kárí ayé pé ìjọba ò dá àwọn ọkùnrin yìí sílẹ̀, àmọ́ wọ́n ń retí pé ìjọba á ronú kàn wọ́n nígbà tí wọ́n bá tún fẹ́ dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀.