Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 22, 2014
TURKMENISTAN

Wọ́n Dá Ìyá Ọlọ́mọ Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan

Wọ́n Dá Ìyá Ọlọ́mọ Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n ní Turkmenistan

Bibi Rahmanova pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀

Aago mẹ́jọ alẹ́ ni Bibi Rahmanova kúrò lẹ́wọ̀n ní September 2, 2014. Wọ́n ní kó máa lọ, àmọ́ kò tíì bọ́ nínú ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án. Láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, àwọn adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Dashoguz gbọ́ ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó pè. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní Bibi ṣì jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, wọ́n fagi lé ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin tí wọ́n rán an lọ, wọ́n sì pàṣẹ pé kí wọ́n dá a sílẹ̀ lójú ẹsẹ̀ àmọ́ wọ́n á ṣì máa ṣọ́ ọ títí ọdún mẹ́rin náà á fi pé. * Ohun tó mú káwọn adájọ́ náà dẹ ẹjọ́ Bibi lójú ni pé obìnrin ni, ó tún ní ọmọ ọdún mẹ́rin kan, kò sì sí lákọọ́lẹ̀ pé ó hùwà ọ̀daràn rí.

August 18 ni ilé ẹjọ́ dá Bibi lẹ́bi ẹ̀sùn èké tí wọ́n lọ́ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀ pé “ó lu ọlọ́pàá,” ó sì “hùwà ìpátá,” àmọ́ ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lẹ́yìn ìgbẹ́jọ́ yẹn. Ṣáájú ìgbà yẹn, ní July 5, àwọn ọlọ́pàá dá Bibi àti Vepa ọkọ rẹ̀ dúró níbi táwọn èèyàn ti ń wọ ọkọ̀ ojú irin ní Dashoguz, wọ́n sì gba ẹrù wọn, tí àwọn ìwé ẹ̀sìn wọn wà nínú rẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n fi Vepa lọ́rùn sílẹ̀. Àmọ́ wọ́n ti Bibi mọ́lé ní August 8. Ṣe ni wọ́n lu Bibi nílùkulù ní ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi sí.

Àlàyé Ṣókí Nípa Ìwà Ìrẹ́jẹ Tó Ń Lọ Lọ́wọ́ ní Turkmenistan

Agbẹjọ́rò Bibi, tó wá láti orílẹ̀-èdè míì sọ pé ara ohun tó mú kí wọ́n dá Bibi sílẹ̀, láìretí pé wọ́n á ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kárí ayé làwọn èèyàn ti ń sọ pé ohun tí ìjọba ṣe yẹn ò bójú mu.

Kì í ṣe òun ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n á kọ́kọ́ ṣe irú ẹ̀ sí lórílẹ̀-èdè Turkmenistan. Wọ́n sábà máa ń tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lójú, ìyẹn sì máa ń fìyà jẹ wọ́n gan-an. Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́jọ ló wà lẹ́wọ̀n torí pé wọn ò yẹ ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n fi àwọn mẹ́fà sẹ́wọ̀n torí ẹ̀rí ọkàn ò jẹ́ kí wọ́n ṣiṣẹ́ ológun, wọ́n sì fi àwọn méjì tó kù sẹ́wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ tí wọn ò mọwọ́ mẹsẹ̀. Ibi tí wọ́n fi wọ́n sí ò dáa rárá, oríṣiríṣi ìyà ni wọ́n sì fi ń jẹ wọ́n.

Ó wúni lórí pé àwọn adájọ́ Ilé Ẹjọ́ Dashoguz ṣe nǹkan kan lórí ọ̀rọ̀ Bibi, àmọ́ wọn ò dẹ́bi fún àwọn tó rẹ́ ẹ jẹ. Àwọn tó mọyì kí wọ́n máa fọ̀wọ̀ ẹni wọni láwùjọ ń retí pé kí àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Turkmenistan fara balẹ̀ wo ohun tó ń lọ lórílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n sì tẹ̀ lé ohun tí ìjọba àpapọ̀ sọ kárí ayé lórí ọ̀rọ̀ yìí kí àwọn aráàlú lè lómìnira ẹ̀sìn.

^ ìpínrọ̀ 2 Ilé ẹjọ́ náà fagi lé ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rin tí wọ́n rán an lọ, àmọ́ wọ́n á ṣì máa ṣọ́ ọ títí ọdún mẹ́rin náà á fi pé. Ọdún mẹ́ta nínú mẹ́rin yẹn ni wọ́n á fi máa wò bóyá ó ṣì ń hùwà dáadáa, wọn ò sì ní jẹ́ kó kúrò nílùú tó ń gbé tàbí kó kó lọ sílùú míì láàárín àkókò yìí láìjẹ́ pé ó kọ́kọ́ gbàyè lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ.