Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MARCH 20, 2019
TURKMENISTAN

Wọ́n Dá Bahram Hemdemov Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Wọ́n Dá Bahram Hemdemov Sílẹ̀ Lẹ́wọ̀n

Ní February 13, 2019, wọ́n dá Bahram Hemdemov kúrò lẹ́wọ̀n ní orílẹ̀-èdè Turkmenistan, ẹni ọdún márùnléláàádọ́ta ni, ó sì ti lo ọdún mẹ́rin ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n ń pè ní Seydi (LB-E/12). Ó tí tún pa dà fojú kan ìyàwó ẹ̀ tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Gulzira, àtàwọn ọmọ wọn mẹ́rin. Wọ́n mú Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov ní March 14, 2015, gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án ò ju pé wọ́n ń ṣe ìjọsìn tí kò wu ìjọba léwu ní ilé rẹ̀ tó wà ní ìlú Turkmenabad, Ilè Ẹjọ́ Ìbílẹ̀ kan ní ìpínlẹ Lebap sọ pé ó jẹ̀bí, wọ́n sì jù ú sẹ́wọ̀n ní May 19, 2015. Ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan ṣíjú àánú wo àwọn ẹlẹ́wọ̀n mélòó kan ní ó kéré tán ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún lásìíkò tí Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov fi wà lẹ́wọ̀n, àmọ́ wọn ò ṣíwèé kàn án rárá, nígbà tó sì jẹ́ pé àwọn tó jẹ̀bi ìpaàyàn wà lára àwọn tí wọ́n dá sílẹ̀ pé kó máa lọ sílé. Ní August 15, 2016, Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov ké gbàjarè sí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí Sí Ẹ̀tọ́ Ọmọniyàn nínú àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-èdè (CCPR), àmọ́ wọn ò tíì sọ nǹkan kan nípa ẹ̀ títí di báyìí. Títí di báyìí, mọ́kànlá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lẹ́wọ̀n ní orílẹ̀-èdè Turkmenistan torí pé wọ́n kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, láìka ẹjọ́ mẹ́wàá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí àjọ CCPR dá pé kí ìjọba jáwọ́ láti máa fìyà jẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọn ò fẹ́ ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn wọn, kí wọ́n má sì jù wọ́n sẹ́wọ̀n.