Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Bahram àti Gulzira ìyàwó rẹ̀

OCTOBER 24, 2016
TURKMENISTAN

Ṣé Wọ́n Máa Dá Bahram Hemdemov Sílẹ̀ Nígbà Tí Ìjọba Bá Tún Ń Dá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Sílẹ̀?

Ṣé Wọ́n Máa Dá Bahram Hemdemov Sílẹ̀ Nígbà Tí Ìjọba Bá Tún Ń Dá Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Sílẹ̀?

Ní February 2016, ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan dá ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn tó wà lẹ́wọ̀n sílẹ̀, àmọ́ wọn ò dá Bahram Hemdemov sílẹ̀. Nígbà tí wọ́n dá Ọ̀gbẹ́ni yìí lẹ́bi pé ọ̀daràn ni, tí wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n, ó pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn àmọ́ kò tó oṣù mẹ́ta lẹ́yìn náà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ lórílẹ̀-èdè Turkmenistan fi fagi lé e. Ní August 15, 2016, agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov bá a kọ̀wé sí Ìgbìmọ̀ Tó Ń Rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn lábẹ́ ìdarí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-èdè.

Wọ́n Gbógun Ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórí Ọ̀rọ̀ Ẹ̀sìn ní Turkmenabad

Ibi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń ṣe ìjọsìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nínú ilé Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov lórílẹ̀-èdè Turkmenabad ni àwọn ọlọ́pàá ti mú un ní March 2015. Ṣe ni àwọn ọlọ́pàá ya wọ ibẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í tú ilé náà láìní ìwé àṣẹ, wọ́n gba àwọn ohun ìní wọn, wọ́n sì ṣe gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ ṣúkaṣùka.

Agbẹjọ́rò Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov sọ pé: “Àwọn ọlọ́pàá yọ Bahram Hemdemov sọ́tọ̀, kí wọ́n lè fìyà jẹ ẹ́ gidigidi torí pé wọ́n fẹ́ fi halẹ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó kù tó ń gbé ní Turkmenabad, kí wọ́n sì ṣẹ̀rù bà wọ́n.” Àmọ́ pẹ̀lú bí àwọn aláṣẹ ṣe fojú Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov gbolẹ̀ tó, kò yẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀.

À Ń Retí Pé Wọ́n Á Dá A Sílẹ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà retí pé ìjọba orílẹ̀-èdè Turkmenistan máa dá Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov sílẹ̀ lẹ́wọ̀n láìpẹ́. Wọ́n máa mọrírì rẹ̀ gan-an tí Ààrẹ Gurbanguly Berdimuhamedov bá dá Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov sílẹ̀ nígbà tó bá tún ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀.

Gulzira, ìyàwó Ọ̀gbẹ́ni Hemdemov àtàwọn ọmọ wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ti sàárò rẹ̀ gan-an, gbogbo wọn àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú wọn ń retí láti pa dà rí i. Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí lórílẹ̀-èdè Turkmenistan ń bẹ ìjọba pé kí wọ́n jẹ́ káwọn máa kóra jọ láti jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀, láìsí pé àwọn aláṣẹ ìlú ń yọ wọ́n lẹ́nu.