MARCH 3, 2022
UKRAINE
Àwọn Ará Ń Fìfẹ́ Hàn Síra Wọn Láìka Ogun Tí Wọ́n Ń Jà ní Ukraine Sí
Ní February 24, 2022, orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà gbógun ja orílẹ̀-èdè Ukraine. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Ukraine lọ́mọdé-lágbà ju ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (129,000) lọ. Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ṣètò Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) kí wọ́n lè ran àwọn ará lọ́wọ́. Bákan náà, àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin fi ìfẹ́ hàn sáwọn Kristẹni bíi tiwọn, ní ti pé wọ́n sapá láti ṣètò ohun tí wọ́n nílò kí wọ́n sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀. Wọn ò fi mọ síbẹ̀ o, wọ́n tún ń ran àwọn aládùúgbò wọn lọ́wọ́ lásìkò wàhálà yìí.
Ọ̀pọ̀ lára àwọn ará wa ló dúró sí orílẹ̀-èdè náà àmọ́ àwọn díẹ̀ yàn láti fí orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. Àwọn èèyàn tó ń fi ìlú náà sílẹ̀ pọ̀ débi pé ìlà tí wọ́n tò sí gùn tó nǹkan bí ọgbọ̀n (30) kìlómítà, kódà àwọn kan lò tó ọjọ́ mẹ́ta sí mẹ́rin kí wọ́n tó lè kọjá lọ́dọ̀ àwọn aṣọ́bodè. Àwọn ará tó ń gbé nítòsí ibodè náà pèsè ohun tí àwọn ará tó wà lórí ìlà náà nílò bí oúnjẹ, omi àti àwọn nǹkan míì. Nígbà tí àwọn ará tó fìlú sílẹ̀ fi máa dé orílẹ̀-èdè míì, wọ́n rí àwọn ará tó gbé àmì jw.org dání, àwọn ará yìí gbà wọ́n tọwọ́tẹsẹ̀, wọ́n tù wọ́n nínú wọ́n sì pèsè ohun tí wọ́n nílò.
Ìpalára Tó Ṣe Fáwọn Ará Wa
Ó bani nínú jẹ́ pé ní March 1, 2022, bọ́ǹbù tí wọ́n jù nílùú Kharkiv pa arákùnrin kan tó jẹ́ adití, ìyàwó ẹ̀ náà sì fara pa yánnayànna
Àwọn arábìnrin mẹ́ta míì náà fara pa
Àwọn akéde tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ti sá kúrò nílé wọn
Ilé méjì ló bà jẹ́ pátápátá
Ilé mẹ́ta ló bà jẹ́ gan-an
Ilé márùndínlógójì (35) ló bà jẹ́ díẹ̀
Gbọ̀ngàn ìpàdé méjì ló bà jẹ́
Kò sí iná àti ẹ̀rọ tó ń múlé móoru, kódà tẹlifóònù ò ṣiṣẹ́, omi ò sì tó nǹkan níbi tí ọ̀pọ̀ àwọn akéde ń gbé
Bá A Ṣe Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́
Wọ́n yan Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ní Ukraine
Ìgbìmọ̀ yìí bá àwọn akéde ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti mẹ́tàdínláàádọ́rin (867) wá ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu tí wọ́n lè máa gbé
Ìgbìmọ̀ yìí ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti pèsè oúnjẹ àti omi
Títí di March 3, 2022, ìròyìn tá a gbọ́ láti orílẹ̀-èdè Ukraine nìyí.
Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ní ọgbọ́n àti òye láti lè fara da àwọn ìṣòro tí wọ́n ń kojú, kí wọ́n sì lè máa fi ìfẹ́ ará hàn sí ara wọ́n.—Òwe 9:10; 1 Tẹsalóníkà 4:9.