Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Gbọ̀ngàn Àpéjọ ní Tiachiv, Ukraine, tí wọ́n ṣètò fún àwọn tógún náà lé kúró nílé wọn

MARCH 8, 2022
UKRAINE

ÌRÒYÌN #1 | Àwọn Ará Ń Fìfẹ́ Hàn Sára Wọn Láìka Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Sí

ÌRÒYÌN #1 | Àwọn Ará Ń Fìfẹ́ Hàn Sára Wọn Láìka Ogun Tó Ń Jà Ní Ukraine Sí

Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìrin wa ń dojú kọ ìṣòro tó le gan-an ní Mariupol, Kharkiv, Hostomel, àtàwọn ìlú míì, torí bí wọ́n ṣe ń ju bọ́ǹbù ní orílẹ̀-èdè Ukraine. Ọ̀pọ̀ wọn ni ò lè jáde nílé fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ kan. Oúnjẹ wọn ti ń tán, kò sì tún rọrùn láti kàn sí wọn torí pé iná mànàmáná àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ti bà jẹ́.

Ó dùn wá gan-an pé Arákùnrin Dmytro Rozdorskyi tó jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n (28) àti alàgbà ní ìjọ Myrnohrad kú nítorí pé ó fara pa nígbà tó tẹ bọ́ǹbù tí wọ́n rì mọ́lẹ̀. Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà dúró ti gbogbo àwọn téèyàn wọn ti kú àtàwọn tó wà làwọn agbègbè tí wọ́n ti ń ju bọ́ǹbù.​—2 Tẹsalóníkà 3:1.

Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tí bọ́ńbù bà jẹ́ ní ìlú Ovruch, lórílẹ̀-èdè Ukraine

Títí di March 7, 2022, ìròyìn tá a gbọ́ láti orílẹ̀-èdè Ukraine nìyí:

Ìpalára tó ṣe fáwọn ará wa

  • Àwọn akéde méjì ló ti kú

  • Àwọn akéde mẹ́jọ ló fara pa

  • Àwọn akéde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànlélógún (20,617) ló fi ilé wọn sílẹ̀ lọ síbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ séwu lórílẹ̀ èdè náà

  • Ilé márùndínlọ́gbọ̀n (25) ló bà jẹ́ pátápátá

  • Ilé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) ló bà jẹ́ gan-an

  • Ilé mẹ́tàléláàádọ́jọ (173) ló bà jẹ́ díẹ̀

  • Gbòngàn Ìjọba márùn-ún ló bà jẹ́

Bá A Ṣe Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́

  • Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù (ìyẹn DRC) mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ló ń báṣẹ́ lọ ní Ukraine

  • Àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àtààbọ̀ (6,548) làwọn DRC bá wá ilé tí wọ́n lè máa gbé níbi tí kò léwu

  • Àwọn akéde ẹgbẹ̀rún méje àti méjọ (7,008) tó sá lọ sórílẹ̀-èdè míì ni àwọn ará ń ràn lọ́wọ́

  • Gbọ̀ngàn Àpéjọ kan àti nǹkan bí ọgbọ̀n Gbọ̀ngàn Ìjọba láwọn agbègbè bíi Chernevtsi, Ivano-Frankivsk, Lviv, àti Transcarpathian lápá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Ukraine, la ti ṣètò fáwọn tí ogun náà lé kúró nílé wọn