MARCH 11, 2022
UKRAINE
ÌRÒYÍN #2 | Àwọn Ará Ń Fìfẹ́ Hàn Síra Wọn Láìka Ogun Tí Wọ́n Ń Jà ní Ukraine Sí
Àkóbá kékeré kọ́ ni ogun tí wọ́n ń jà ti fà láwọn agbègbè kan, irú bí ìlú Mariupol. Bí àpẹẹrẹ, kò sí iná mọ̀nàmọ́ná, bẹ́ẹ̀ ni ko sí fóònù àti Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀pọ̀ ilé ni wíńdò ẹ̀ ti bà jẹ́, bákan náà kò fi bẹ́ẹ̀ sí oúnjẹ àti omi. Ohun tó ju ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,500) àwọn ará ni ò ráyè kúrò nílùú Mariupol. Àmọ́ láwọn ìlú bíi Bucha, Chernihiv, Hostomel, Irpin, Kyiv, àti Sumy, wọ́n fáwọn èèyàn láǹfààní láti jáde. Ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fáwọn ará wa kan láti lọ sáwọn agbègbè míì tí ò fi bẹ́ẹ̀ léwu.
Alàgbà kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì (36), tó sì tún jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sá kúrò nílùú Hostomel pẹ̀lú ìyàwó àtàwọn òbí rẹ̀. Ó ṣàlàyé ohun tójú ẹ̀ rí nígbà tógun náà bẹ̀rẹ̀, ó ní:
“Ọkọ̀ Helicopter ń fò lókè ilé wa. Gbogbo ìgbà ni ọkọ̀ àwọn sójà ṣì ń lọ káàkiri àdúgbò wa. Àwọn sójà já wọlé wa, àmọ́ inú àjà ilẹ̀ la wà nígbà yẹn. Ní ọ̀kan nínú wọn bá bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn sí àjà ilẹ̀ níbi tá a wà, ọta ìbọn náà ba báàgì pàjáwìrì màámi, àmọ́ kò bà wá. Fún nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta sí mẹ́rin la fi ń gbúròó bọ́ǹbù àti ìbọn lókè orí wa, àmọ́ a ò mira, a ò sì sọ ohunkóhun níbi tá a fara pamọ́ sí. . . . Nígbà tá a bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò lọ́jọ́ kejì, ṣe ni ìjà bẹ̀rẹ̀ nítòsí wa. Bá a ṣe ń lọ là ń pàdé àwọn ọkọ̀ ìjà ogun . . . Ìrìn àjò náà léwu gan-an, àmọ́ tá a bá ní ká dúró, ìyẹn ló léwu jù.
“Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ti yí ìgbésí ayé wa pa dà. Torí ó ti jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. Bí àpẹẹrẹ, a ti rí i pé kò yẹ ká máa ṣàníyàn nípa ọ̀la. Yàtọ̀ síyẹn, ká jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun díẹ̀ tẹ́ wa lọ́rùn, ká sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà láwọn àkókò tí nǹkan bá nira.”
A mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run wa ń rí gbogbo ìṣòro táwọn ará wa ń dojú kọ lórílẹ̀-èdè Ukraine. Ó sì dájú pé ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́.—2 Pétérù 2:9.
Títí di March 10, 2022, ìròyìn tá a gbọ́ láti orílẹ̀-èdè Ukraine nìyí:
Ìpalára Tó Ṣe Fáwọn Ará Wa
Akéde méjì ló ti kú
Akéde mẹ́jọ ló fara pa
Akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,407) ló filé wọn sílẹ̀ lọ síbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu lórílẹ̀-èdè náà
Ilé mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ló bà jẹ́ pátápátá
Ilé mọ́kàndínlọ́gọ́ta (59) ló bà jẹ́ gan-an
Ilé tó jẹ́ ọgọ́rùn-ún méjì àti méjìlélógún ló bà jẹ́ díẹ̀
Gbọ̀ngàn Ìjọba méje ló bà jẹ́
Bá A Ṣe Ran Àwọn Ará Wa Lọ́wọ́
Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù (DRC) mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27) ni wọ́n ṣètò ní Ukraine
Ìgbìmọ̀ yìí ti bá àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ààbọ̀ (10,566) wá ibi tí ò fi bẹ́ẹ̀ léwu láti gbé
Àwọn akéde tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (9,635) tó sá lọ sórílẹ̀-èdè míì làwọn ará ti ràn lọ́wọ́