Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 31, 2019
UKRAINE

Ilé Ẹjọ́ ECHR Ṣèdájọ́ Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Orílẹ̀-Èdè Ukraine

Ilé Ẹjọ́ ECHR Ṣèdájọ́ Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba ní Orílẹ̀-Èdè Ukraine

Ní September 3, 2019, Ìgbìmọ̀ Ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) ṣèdájọ́ kan tó dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre ní ìlú Kryvyi Rih, lórílẹ̀-èdè Ukraine. Ilé Ẹjọ́ náà dá ìgbìmọ̀ ìlú Kryvyi Rih lẹ́bi pé wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ kọ̀ láti yọ̀ǹda fáwọn ará wa pé kí wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Àwọn ara rèé níwájú ilẹ̀ tí wọ́n fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí, ní ìlú Kryvyi Rih, lórílẹ̀-èdè Ukraine

Ìgbìmọ̀ Ìdájọ́ sọ pé ìgbìmọ̀ ìlú náà gbọ́dọ̀ san ẹgbẹ̀rún méje (7,000) owó euro (iye tó lé ní mílíọ̀nù méjì ààbọ̀ owó náírà) fún àwọn ìjọ méjèèjì tó ni Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Owó tí wọ́n bù lé wọn yìí jẹ́ owó ìtanràn àti owó tí àwọn ìjọ náà ti ná lẹ́nu ẹjọ́ náà. Wọ́n ní ìgbìmọ̀ ìlú ti tàpá sí Àpilẹ̀kọ Kẹsàn-án nínú Àdéhùn Àjọṣe ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn (tó dáàbò bo òmìnira èrò, ẹ̀rí ọkàn àti ẹ̀sìn) àti Àpilẹ̀kọ Kìíní nínú Àkọsílẹ̀ Kìíní (tó fún àwọn aráàlú ní ẹ̀tọ́ láti ní ilẹ̀ àti ilé wọn). Oṣù mẹ́ta ni ìjọba orílẹ̀-èdè Ukraine ní láti ta ko ìpinnu Ìgbìmọ̀ Ìdájọ́ náà nípa pípe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí ilé ẹjọ́ Ìgbìmọ̀ Tó Ga Jù Lọ ní Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù.

Ó ti lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) báyìí tí ìjọ méjèèjì tó wà ní ìlú Kryvyi Rih tí kọ́kọ́ kọ̀wé láti gbàṣẹ pé àwọn fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní August 9, 2004, wọ́n ra ilé gbígbé tó wà lórí ilẹ̀ kékeré kan tó wà lábẹ́ àbójútó ìlú náà, lẹ́yìn yẹn ni wọ́n kọ̀wé láti gbàṣẹ fún yíyá ilẹ̀ náà lò fún ọdún márùn-ún kí wọ́n lè kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sórí rẹ̀. Ìgbìmọ̀ ìlú kọ́kọ́ fọwọ́ sí ìwé wọn ní September 28, 2005. Wọ́n wá rán àwọn ará wa létí pé àwọn aṣojú ìjọba kan gbọ́dọ̀ ṣe àyẹ̀wò àwòrán ilé tí wọ́n fẹ́ kọ́ náà kí wọ́n tó lè láṣẹ láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé náà.

Àwọn ará wa ya àwòrán ilé náà, gbogbo àwọn aláṣẹ ìjọba tó yẹ kó fọwọ́ sí i buwọ́ lù ú, wọ́n sì gbé e lọ sọ́dọ̀ ìgbìmọ̀ ìlú ní August 23, 2006 kí wọ́n lè fún wọn láṣẹ láti bẹ̀rẹ̀ sí kọ́lé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òfin sọ pé oṣù kan péré ni ìgbìmọ̀ ìlú ní láti sọ ìpinnu rẹ̀ di mímọ̀, wọn ò sọ ohunkóhun nípa ìwé táwọn ará gbé lọ síwájú wọn. Kódà lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ ẹkùn ìpínlẹ̀ jẹ́rìí sí i pé ohun tí ìgbìmọ̀ ìlú ṣe yìí kò bófin mu, ìgbìmọ̀ náà ṣì kọ̀ láti buwọ́ lu ìwé náà kí iṣẹ́ lè bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn ilé ẹjọ́ míì náà tí kọ̀ láti ṣe ohun tó tọ́, àwọn ará gbé ẹjọ́ náà lọ síwájú Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù ní April 13, 2010.

Inú wa dùn pé Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù dá àwọn ará wa tó wà ní Kryvyi Rih láre. Àdúrà wa ni pé kí ìdájọ́ Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù yìí mú kó túbọ̀ rọrùn fún àwọn ara wá tó bá fẹ́ kọ́ ibi ìjọsìn Jèhófà ní àwọn ilẹ̀ táwọn aláṣẹ ti ń fi irú òmìnira bẹ́ẹ̀ dù wọ́n.​—Sáàmù 118:​5-9.