Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọ́n ń kí Arákùnrin David Splane, ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àti ìyàwó rẹ̀ káàbọ̀ ní Pápákọ̀ Òfúrufú Lviv Danylo Halytskyi.

NOVEMBER 9, 2018
UKRAINE

Ìṣọ̀kan àti Aájò Àlejò Wà Láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nígbà Àkànṣe Àpéjọ ní Ukraine

Ìṣọ̀kan àti Aájò Àlejò Wà Láàárín Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nígbà Àkànṣe Àpéjọ ní Ukraine

Ní July 6 sí 8, 2018, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ukraine kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará káàbọ̀ síbi àkànṣe àpéjọ tó wáyé ní ìlú Lviv, lórílẹ̀-èdè Ukraine. Ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (3,300) èèyàn láti orílẹ̀-èdè mẹ́sàn-án tó wá sí Ukraine láti wá gbádùn ètò tó dá lórí Bíbélì náà, àkòrí ètò náà ni “Jẹ́ Onígboyà”! Àwọn ará ní Ukraine sì ṣaájò wọn gan-an.

Oṣù April 2017 ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í múra sílẹ̀ fún àpéjọ náà, lóṣù mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) tó tẹ̀ lé e, àwọn ará tó wà lágbègbè náà yọ̀ǹda ara wọn láti ṣètò àpéjọ náà àti bí wọ́n ṣe máa bójú tó àwọn tó máa wá sí àpéjọ náà. Àwọn tó wá síbi àpéjọ náà rí lára àwọn àṣà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ táwọn èèyàn ilẹ̀ Ukraine ní, irú bí ijó àti orin wọn àtàwọn oúnjẹ ìbílẹ̀ wọn. Wọ́n ṣètò báwọn èèyàn ṣe máa lọ síbi tí wọ́n ń ko àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sí, àwọn ilé ńlá ayé àtijọ́ àti bí wọ́n ṣe máa lọ wo lára òkè Carpathian tó jẹ́ àwòṣífìlà. Ètò kan tó tún ṣàrà ọ̀tọ̀ ni báwọn tó wá ṣe láǹfààní láti bá àwọn ará ní Ukraine lọ sóde ẹ̀rí.

Pápá ìṣeré kan ní ìlú Lviv ni wọ́n ti ṣe àpéjọ náà, àwọn tó wá síbẹ̀ sì ju ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000). Wọ́n tàtaré àwọn apá tó jẹ́ lájorí nínú àpéjọ náà sí pápá ìṣeré mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) míì àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba káàkiri orílẹ̀-èdè náà, iye gbogbo àwọn tó wá sí àpéjọ náà lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùnlélọ́gọ́fà (125,000), àwọn ẹgbẹ̀rún kan ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ogún (1,420) ló sì ṣèrìbọmi.

Ivan Riher tó jẹ́ aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì ní Ukraine, sọ pé: “A ti ń fojú sọ́nà fún àpéjọ pàtàkì yìí, ó sì ń wù wá láti kí àwọn ará láti àwọn orílẹ̀-èdè míì káàbọ̀. A gbádùn bí a ṣe fi àwọn nǹkan ilẹ̀ wa ṣe àwọn tó wá lálejò, èyí sì mú ká rí bí ìṣọ̀kan àti ìgboyà tó wà láàárín àwọn ará wa kárí ayé ṣe ń pọ̀ sí i.”—Sáàmù 133:1.

 

Iye àwọn tó wá sí pápá ìṣeré náà ní ìlú Lviv jẹ́ 25,489.

Ọ̀kan lára àwọn tó dàgbà jù lọ nínú àwọn 1,420 tó ṣèrìbọmi.

Ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́ tó ṣèrìbọmi ní àpéjọ náà.

Wọ́n pín àwọn ará tó wà ní Ukraine mọ́ àwọn tó wá láti ilẹ̀ míì kí wọ́n lè jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí bí wọ́n ṣe ń pe àwọn aráàlú síbi àpéjọ náà.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì gba Lviv Opera House tó ní gbàgede tó tóbi jù ní ìlú náà. Àwọn tó wá sí àpéjọ náà gbádùn orin àti ijó ìbílẹ̀ àwọn ará ilẹ̀ Ukraine. Orin “Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ” ni wọ́n fi parí ètò tí wọ́n ṣe nírọ̀lẹ́ náà.

Àwọn ará lórílẹ̀-èdè Ukraine ń jó ijó Romany ní Ilé Ńlá Svirzh.

Àwọn ará lórílẹ̀-èdè Ukraine lo àwọn àkọlé níparí àpéjọ náà láti fi hàn pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn ará tó wá láti àwọn ilẹ̀ míì.