OCTOBER 15, 2018
UKRAINE
Wọ́n Fòfin De Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní “Donetsk People’s Republic”
Ní September 26, 2018, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní “Donetsk People’s Republic” (DPR) sọ pé “agbawèrèmẹ́sìn” ni àjọ ẹ̀sìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, torí náà wọ́n fòfin de iṣẹ́ wa. Kò sí ìkankan nínú àwọn tó pe ẹjọ́ yìí, títí kan Ilé tó dá ẹjọ́ náà tó béèrè ọ̀rọ̀ lẹ́nu Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan nígbà tí ẹjọ́ náà ń lọ lọ́wọ́. Ìfòfindè yìí ni ìgbésẹ̀ tuntun tí wọ́n gbé nínú bí wọ́n ṣe ń ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lágbègbè yìí torí ẹ̀sìn wọn.
Láti àárín ọdún 2017 tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ nílẹ̀ DPR ti sọ pé lára àwọn ìtẹ̀jáde wa jẹ́ ti àwọn “agbawèrèmẹ́sìn,” ńṣe ni nǹkan túbọ̀ ń burú sí i fún àwọn ará wa láwọn agbègbè kan ní Donetsk àti Luhansk, ní ìlà oòrùn ilẹ̀ Ukraine. Kí ọdún yẹn tó parí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà táwọn ọlọ́pàá mú kí wọ́n lè da ìbéèrè bò wọ́n lé ní àádọ́sàn-án (170). Àwọn aláṣẹ agbègbè náà sì tún ṣètò bí wọ́n ṣe ń gba àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ní kọ̀ọ̀kan. Iye gbogbo Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n ti gbà títí di August 29, 2018 jẹ́ mẹ́rìnlélógún (16).
Lójú gbogbo àtakò ẹ̀sìn yìí, àwọn ará wa láwọn agbègbè yìí gbẹ́kẹ̀ lé ‘Ọlọ́run ìgbàlà wa.’—Sáàmù 18:46.