JULY 1, 2019
UKRAINE
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-Èdè Ukraine Ṣàfihàn Bíbélì
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Ukraine ṣe àfihàn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a mú jáde ní Èdè Adití ti Rọ́síà, aṣeyọrí tó lápẹẹrẹ lèyí sì jẹ́ nínú iṣẹ́ ìtúmọ̀ tí à ń ṣe. Àfihàn náà bẹ̀rẹ̀ ní October 7, 2018 ní ìlú Lviv, a sì ṣe é títí di June 7, 2019. Àwọn ìlú míì tá a ti ṣe àfihàn náà ni Kharkiv, Kyiv, Odesa àti Dnipro.
Kí a tó ṣe àfihàn yìí, àwọn ìjọ tó ń sọ èdè adití pín ìwé ìkésíni fáwọn adití àtàwọn tí kò gbọ́ran dáadáa lágbègbè tí àfihàn náà ti máa wáyé, wọ́n sì tún fàwọn fídíò hàn wọ́n. Yàtọ̀ síyẹn, Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde ní ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Ukraine pín ìwé ìkésíni fún àwọn onímọ̀ ẹ̀kọ́, àwọn oníròyìn àtàwọn aláṣẹ.
Àwọn tó wá síbi àfihàn tá a kọ́kọ́ ṣe ní Lviv City Deaf Club rí oríṣiríṣi àwọn ètò tá a ṣe táwọn adití lè lò láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, irú bí ètò JW Library Sign Language®. Àwọn tó wá tún rí àfihàn kan tó ní oríṣiríṣi Bíbélì tí wọ́n ti lò láti ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún, látorí àwọn ìwé àkájọ títí dé àwọn ìwé òde òní. Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ohun tó wà níbẹ̀ ni Bíbélì kan tó ti wà látọdún 1927.
Inú wa dùn pé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti wà ní Èdè Adití ti Rọ́síà. Ó dá wa lójú pé ó máa jẹ́ kó rọrùn fáwọn tó ń sọ èdè náà láti ní ìmọ̀ tó péye nípa Bíbélì.—Mátíù 5:3.