MARCH 24, 2017
UKRAINE
Ilé Ẹjọ́ Gíga ní Ukraine Túbọ̀ Jẹ́ Kí Àwọn Aráàlú Lómìnira Láti Máa Kóra Jọ ní Àlàáfíà
Ní September 8, 2016, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin lórílẹ̀-èdè Ukraine sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn lẹ́tọ̀ọ́ láti pàdé pọ̀ ní àlàáfíà láìsí pé àwọn aláṣẹ ń dí wọn lọ́wọ́. Ilé Ẹjọ́ yìí fagi lé apá kan lára Òfin Ilẹ̀ Ukraine tó dá lórí Òmìnira Ẹ̀rí Ọkàn àti Àwọn Ẹlẹ́sìn (ìyẹn Òfin Ẹ̀sìn) tí wọ́n ṣe lọ́dún 1991, tó sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gba “àṣẹ” lọ́wọ́ Ìjọba kí wọ́n tó lè pàdé láti jọ́sìn nínú ilé tí wọ́n bá yá. Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin sọ pé òfin yìí ta ko ìlérí tí ìjọba ṣe lábẹ́ òfin pé àwọn á jẹ́ káwọn ẹlẹ́sìn máa pàdé pọ̀ ní àlàáfíà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine fara mọ́ ẹjọ́ tí Ilé Ẹjọ́ dá yìí, torí pé ó máa ń ṣòro fún wọn gan-an láti rí ilé tí wọ́n á ti jọ́sìn yá.
Àwọn Aláṣẹ Ò Gbà Wọ́n Láyè Láti Jọ́sìn
Látìgbà tí ìjọba ti ṣe Òfin Ẹ̀sìn, àwọn aláṣẹ kan ti ń lo òfin náà bó ṣe wù wọ́n, wọ́n ń lò ó láti fagi lé àdéhùn táwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣe pẹ̀lú àwọn tó fẹ́ yá wọn nílé tí wọ́n á ti ṣe ìjọsìn. Ohun kan ṣẹlẹ̀ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 2012. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àríwá ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Ukraine ń wọ̀nà fún àpéjọ ọlọ́jọ́ mẹ́ta kan tí wọ́n fẹ́ ṣe nílùú Sumy. Wọ́n ti lọ yá pápá ìṣeré ìlú, wọ́n sì ti tọwọ́ bọ̀wé, gbogbo ètò ti ń lọ ní pẹrẹu. Bí òfin ṣe sọ, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ọ̀rọ̀ àpéjọ tí wọ́n fẹ́ ṣe tó àwọn aláṣẹ létí. Nígbà tó wá ku oṣù kan péré kí àpéjọ náà bẹ̀rẹ̀, Àjọ Ìlú Sumy sọ pé, ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Ẹ̀sìn, kí àwọn Ẹlẹ́rìí fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn aláṣẹ létí nìkan kò tó. Àjọ náà sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn kí wọ́n tó lè lo pápá ìṣeré náà, wọn sì kọ̀ láti fún wọn láṣẹ ọ̀hún.
Láàárín àkókò kékeré tó kù yẹn, ṣe làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò láti ṣe àpéjọ náà nílùú Kharkiv, tó wà ní nǹkan bíi igba [200] kìlómítà sílùú Sumy. Àyípadà yìí mú kó di dandan fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ [3,500] láti bẹ̀rẹ̀ sí í tètè wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ni ò lè rìnrìn àjò lọ sílùú Kharkiv láti gbádùn ìpàdé pàtàkì yìí torí pé ara ti dara àgbà, ara àwọn míì ò sì le. Àwọn kan ò lè lọ torí wọn ò fún wọn láyè níbi iṣẹ́, àwọn míì ò sì lówó tó máa gbé wọn dé ìlú Kharkiv. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, Àjọ Ìlú Sumy ò tún jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí ṣe àpéjọ níbi pápá ìṣeré yẹn, wọ́n ní Òfin Ẹ̀sìn ò fàyè gbà á.
Illia Kobel, tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Lviv, ṣàlàyé pé: “Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí irú ohun tó ṣẹlẹ̀ nílùú Sumy máa ṣẹlẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń ṣòro fún wa láti yá ilé tá a máa lò fún ìjọsìn wa.” Bí àpẹẹrẹ, ní March 2012, àwọn aláṣẹ nílùú Vinnytsia ò jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ìpàdé nínú gbọ̀ngàn kan tí wọ́n yá, ó wá di pé kí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá torí ọ̀rọ̀ ọ̀hún ti bọ́ sórí. Òmíràn tún ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn oṣù díẹ̀. Àwọn aláṣẹ ò jẹ́ kí ìjọ Mohyliv-Podilskyi ṣe ìjọsìn tí wọ́n máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nínú ilé kan tí wọ́n yá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ọdún mẹ́ta tí wọ́n ti ń pàdé láti jọ́sìn nínú ilé náà. Torí pé àwọn ará ìjọ náà ò rí ibòmíì tó bójú mu láti pàdé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pàdé ní ilé ara wọn. Ó di pé kí wọ́n máa fún ara wọn mọ́bẹ̀, torí kò gbà wọ́n dáadáa.
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ní February 2015, Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Ìlú Vinnytsia sọ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rú òfin. Ìgbìmọ̀ náà sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rúfin bí wọ́n ṣe kọ̀ láti gbàṣẹ kí wọ́n tó máa ṣe ìjọsìn wọn nínú àwọn ilé tí kì í ṣe ilé tí wọ́n dìídì kọ́ fún ìjọsìn. Wọ́n ní kí wọ́n fi tó àwọn aláṣẹ létí pé àwọn fẹ́ lo ilé kan láti jọ́sìn nìkan kò tó.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Wá Ọ̀nà Láti Yanjú Ọ̀rọ̀ Òfin Tó Ta Kora
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ìjọba kì í sábà yọ àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́nu pé kí wọ́n máà kóra jọ sí ilé ìjọsìn wọn. Àmọ́ tí wọ́n bá fẹ́ ṣe àwọn ìpàdé àkànṣe àbí àpéjọ àgbègbè, ó máa ń gba pé kí wọ́n yá ilé tó máa lè gba ọ̀pọ̀ èèyàn. Òfin orílẹ̀-èdè Ukraine gba àwọn ẹlẹ́sìn láyè láti kóra jọ ní àlàáfíà sínú ilé tí wọ́n yá, tí wọ́n bá ṣáà ti kọ́kọ́ fi tó àwọn aláṣẹ létí. Ọ̀gbẹ́ni Kobel sọ pé: “Ohun tó ń fa ìṣòro fún wa gan-an ni ohun tí Òfin Ẹ̀sìn sọ, èyí tí wọ́n fi ń ká wa lọ́wọ́ kò. Bẹ́ẹ̀, òfin yìí ta ko òfin ìjọba, tí kò sọ pé dandan ni ká gbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ. Kí ọ̀rọ̀ náà lè lójú, a gbé e dé ọ̀dọ̀ Kọmíṣọ́nnà fún Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Ilẹ̀ Ukraine, tí wọ́n tún ń pè ní Ombudsman tàbí Alárinà.”
Iṣẹ́ Alárinà yìí ni láti rí i pé gbogbo àwọn aráàlú ní Ukraine gbádùn ẹ̀tọ́ tí wọ́n ní lábẹ́ òfin orílẹ̀-èdè náà. Lẹ́yìn tí Alárinà náà ṣàyẹ̀wò ohun tójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rí, ó gbà pé òfin orílẹ̀-èdè náà àti Òfin Ẹ̀sìn ta kora. Òfin orílẹ̀-èdè fọwọ́ sí i pé àwọn èèyàn lè kóra jọ láti jọ́sìn nínú ilé tí wọ́n yá, tí wọ́n bá ṣáà ti fi tó àwọn aláṣẹ létí ṣáájú. Àmọ́ Òfin Ẹ̀sìn sọ pé kò bófin kí àwọn ẹlẹ́sìn kóra jọ fún ìjọsìn nínú ilé tí wọ́n yá àfi tí wọ́n bá kọ́kọ́ gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ, ó kéré tán, ọjọ́ mẹ́wàá ṣáájú ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe.
Ní October 26, 2015, ọ́fíìsì Alárinà kọ̀wé sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Orílẹ̀-èdè Ukraine, wọ́n sọ pé apá kan nínú Òfin Ẹ̀sìn náà kò bófin orílẹ̀-èdè mu. Nínú ìwé tí wọ́n kọ, wọ́n sọ pé gbogbo aráàlú ló lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin láti kóra jọ fún ìjọsìn ní àlàáfíà. Wọ́n yànnàná ọ̀rọ̀ yìí, wọ́n ní: “Ìjọba ò gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀nà tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ ṣèdíwọ́ fún ẹ̀tọ́ àwọn èèyàn láti kóra jọ fún ìjọsìn.” Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ukraine náà ti ohun tí Alárinà sọ lẹ́yìn, wọ́n kọ̀wé sí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin láti ṣàlàyé ohun tójú wọn ń rí bí wọ́n ṣe ń yá ilé tí wọ́n á ti máa pàdé fún ìjọsìn.
Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Fagi Lé Òfin Tó Ta Ko Òfin Ilẹ̀ Náà
Ní September 8, 2016, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ṣèdájọ́ pé kò sí òfin tó gbọ́dọ̀ ṣèdíwọ́ fún ẹ̀tọ́ táwọn èèyàn ní lábẹ́ òfin láti kóra jọ ní àlàáfíà tí wọ́n bá ti fi tó àwọn aláṣẹ létí. Yàtọ̀ sí òfin orílẹ̀-èdè wọn, wọ́n tún sọ̀rọ̀ nípa Àpilẹ̀kọ 9 nínú àdéhùn European Convention on Human Rights, tó sọ pé èèyàn ní òmìnira ẹ̀sìn, àti Àpilẹ̀kọ 11, tó sọ pé àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti kóra jọ fún ìjọsìn láìsí pé Ìjọba ń dí wọn lọ́wọ́ tí kò bá sí ìdí pàtàkì tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ilé ẹjọ́ náà sọ pé Apá 5 lábẹ́ Àpilẹ̀kọ 21 nínú Òfin Ẹ̀sìn tí wọ́n ṣe lọ́dún 1991 ta ko òfin, èyí tó sọ pé àwọn ẹlẹ́sìn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbàṣẹ lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ kí wọ́n tó ṣe ìjọsìn nínú ilé tí wọ́n bá yá.
Ọ̀rọ̀ Yanjú, Àwọn Èèyàn sì Fara Mọ́ Ibi Tó Já Sí
Ní báyìí, kò ságbára lọ́wọ́ àwọn aláṣẹ mọ́. Àwọn kọ́ ló ń pinnu mọ́, bóyá àwọn ẹlẹ́sìn máa lè ṣe ìjọsìn nínú ilé tí wọ́n yá. Òfin ilẹ̀ Ukraine ti sọ pé tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ṣáà ti lè fi tó àwọn aláṣẹ létí ṣáájú pé àwọn fẹ́ yá ilé kan táwọn ti máa ṣe ìjọsìn, àwọn aláṣẹ ò lè dí wọn lọ́wọ́.
Ọ̀gbẹ́ni Kobel gbẹnu sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogóje [140,000] tí wọ́n wà lórílẹ̀-èdè Ukraine, ó ní: “Ìpinnu tí Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ṣe yìí ti jẹ́ ká túbọ̀ lómìnira láti máa kóra jọ ní àlàáfíà. Inú wa dùn pé àwọn aláṣẹ ò ní dí wa lọ́wọ́ mọ́ tá a bá fẹ́ yá ilé tá a ti máa ṣe ìjọsìn.”