Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 13, 2016
UKRAINE

Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Wọ́n Gbà Mọ́ Wọn Lọ́wọ́ ní Àgbègbè Donetsk àti Luhansk ní Ukraine

Gbọ̀ngàn Ìjọba Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Wọ́n Gbà Mọ́ Wọn Lọ́wọ́ ní Àgbègbè Donetsk àti Luhansk ní Ukraine

Àgbègbè Donetsk

ÌLÚ HORLIVKA—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní ìparí oṣù June, ọdún 2014, àwọn ọkùnrin tó dira ogun ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní No. 3A, ládùúgbò Viliamsa Akademika, wọ́n jí àwọn ohun èlò tó ń báná ṣiṣẹ́ tó wà níbẹ̀, wọ́n sì fi kọ́kọ́rọ́ míì sí àwọn ilẹ̀kùn ibẹ̀. Wọ́n ń fi ibẹ̀ ṣe bárékè wọn.

  • Ní April 13, 2015, wọ́n dá ilé náà pa dà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìlú Horlivka, No. 75, Àdúgbò Akademika Koroliova

ÌLÚ HORLIVKA—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní July 5, 2014, àwọn ọkùnrin tó dira ogun gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí. Wọ́n ń fi ṣe bárékè wọn, wọ́n sì ń kó ohun ìjà pa mọ́ síbẹ̀, àmọ́ wọ́n pa á tì ní September 2014. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá pa dà síbẹ̀, wọ́n sì ń bá ìjọsìn wọn lọ níbẹ̀.

  • Ní October 12, 2014, àwọn ológun da ìjọsìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe rú nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, wọ́n sì ní kí gbogbo àwọn tó wá dáwọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe dúró. Wọ́n ní ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nìkan lòfin fọwọ́ sí lágbègbè náà, wọ́n sì sọ pé àwọn máa tó “rẹ́yìn gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Àwọn ọkùnrin náà ń fi Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí ṣe bárékè wọn.

Ìlú Donetsk, No.10, Àdúgbò Karamzina

ÌLÚ DONETSK—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní August 13, 2014, àwọn ọkùnrin tó dira ogun ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ibẹ̀ ṣe bárékè wọn.

  • Ní August 19, 2014, àwọn ọkùnrin náà jí ẹ̀rọ tó ń gbé ohùn jáde, wọ́n sì kúrò níbẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá pa dà síbẹ̀, wọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìjọsìn wọn nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà.

  • Ní October 18, 2014, lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ìsìn tán, àwọn aṣojú ẹgbẹ́ Fourth Oplot Battalion lọ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, wọ́n sì kéde fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ pé àwọn máa gba ilé náà.

  • Ní November 18, 2014, àwọn ológun ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tọwọ́ bọ̀wé pé àwọn ti fọwọ́ sí i kí Gbọ̀ngàn Ìjọba náà di ti Ọ̀gágun tó ń bójú tó Àgbègbè Petrovskyi àti Kirovskyi. Wọ́n ti ń fi ibẹ̀ ṣe bárékè wọn.

Ìlú Horlivka, No. 4, Àdúgbò Hertsena

ÌLÚ HORLIVKA—Àwọn aráàlù ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní September 30, 2014, iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan nílùú yìí fọ̀rọ̀ wá ẹni tí wọ́n sọ pé ó ni Gbọ̀ngàn Ìjọba náà báyìí lẹ́nu wò, ẹni náà sì sọ pé ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n ti gbà á káwọn lè máa fi ṣe ibi tí wọ́n ti ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń kan ẹ̀ṣẹ́. Látọdún 2013, léraléra ni wọ́n ti ń yọ àwọn Ẹlẹ́rìí lẹ́nu ní Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, tí wọ́n ń ba nǹkan jẹ́ níbẹ̀, tí wọ́n sì máa ń fẹ́ dáná sun ilé náà. June 5, 2014 ni wọ́n gbìyànjú ẹ̀ kẹ́yìn láti sọná síbẹ̀.

ÌLÚ DONETSK—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní October 26, 2014, àwọn ológun láti ẹgbẹ́ Shakhtar Battalion tó wà lábẹ́ ẹgbẹ́ Donetsk People’s Republic (DPR) ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, wọ́n sì ti ń fi ibẹ̀ ṣe bárékè wọn báyìí.

Ìlú Zhdanivka, No. 14, Àdúgbò Komsomolska

ÌLÚ ZHDANIVKA—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní October 27, 2014, àwọn ológun nínú ẹgbẹ́ Horlivka gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, wọ́n ní ọ̀gágun kan ló pàṣẹ pé káwọn wá gbà á. Igbákejì Ọ̀gágun Ẹgbẹ́ Horlivka sọ pé ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nìkan lòfin fọwọ́ sí lágbègbè náà, pé òfin de gbogbo ẹ̀sìn yòókù.

  • Ní November 21, 2014, ọ̀gágun ẹgbẹ́ míì gbà Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, ó sì sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé àwọn ọmọ abẹ́ òun lá máa lò ó báyìí.

  • Ní November 20, 2015, àwọn ológun náà fi ibẹ̀ sílẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá pa dà síbẹ̀.

Ìlú Telmanove, No. 112, Àdúgbò Pervomaiska

ÌLÚ TELMANOVE—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní November 4, 2014, àwọn ọkùnrin tó dira ogun ya wọ ibẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ ibẹ̀.

  • Ní December 11, 2014, àwọn ọkùnrin náà kó ohun ìjà wọnú ilé náà, wọ́n sì ti ń fi ibẹ̀ ṣe bárékè wọn báyìí.

Ìlú Makiivka, No. 17, Àdúgbò Pecherska

ÌLÚ MAKIIVKA—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, àmọ́ wọ́n pa dà fi ibẹ̀ sílẹ̀.

  • Ní November 5, 2014, àwọn ológun láti ẹgbẹ́ Rus Battalion ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí. Wọ́n pàṣẹ pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí fún àwọn ní kọ́kọ́rọ ibẹ̀, wọ́n sì sọ pé àwọn ò fẹ́ rí ẹsẹ̀ wọn níbẹ̀ mọ́. Lọ́jọ́ kejì, igbákejì ọ̀gágun ẹgbẹ́ náà yọ pátákó tí wọ́n kọ “Gbọ̀ngan Ìjọba” sára rẹ̀, ó sì fi àsíá ẹgbẹ́ náà rọ́pò rẹ̀.

  • Ní November 26, 2014, àwọn ológun yẹn pa ilé náà tì.

ÌLÚ HORLIVKA—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, wọ́n wá pa á tì, àmọ́ wọ́n tún gbà á nígbà tó yá.

  • Ní November 29, 2014, àwọn ọkùnrin tó dira ogun ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní No. 105-A ládùúgbò Vitchyzniana, wọ́n sì kéde fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ pé àwọn máa gbà á. Ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin náà sọ pé ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì nìkan ni ẹgbẹ́ DPR fọwọ́ sí lágbègbè náà. Àwọn ọkùnrin náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣọ́ ilé náà, wọn ò sì jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí pa dà síbẹ̀. Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, wọ́n kúrò níbẹ̀.

  • Ní July 22, 2016, àwọn ológun tún wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba náa, wọ́n sì ní kí gbogbo àwọn tó wá síbẹ̀ jáde lójú ẹsẹ̀. Àwọn ọkùnrin náà wá tú gbogbo ilé náà.

Ìlú Zuhres, No. 1, Àdúgbò Cherniakhovskoho

ÌLÚ ZUHRES—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní December 20, 2014, ọ̀gágun ìlú kéde pé òun máa gba Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Ó pàṣẹ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n fún òun ní kọ́kọ́rọ́ ibẹ̀, òun ò sì gbọ́dọ̀ rẹ́sẹ̀ wọn níbẹ̀ mọ́.

  • Ní April 19, 2015, wọ́n dá ilé náà pa dà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÌLÚ DONETSK—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní February 1, 2015, àwọn ọkùnrin tó dira ogun wá sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Wọ́n ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi kọ́kọ́rọ́ ibẹ̀ lé àwọn lọ́wọ́, kí wọ́n sì fọwọ́ síwèé pé àwọn ológun lá máa lo Gbọ̀ngàn Ìjọba náà ní gbogbo àsìkò tógun fi ń jà.

  • Ní February 29, 2016, wọ́n dá ilé náà pa dà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ó gba pé kí wọ́n tún un ṣe kí wọ́n tó tún lè máa jọ́sìn níbẹ̀.

ÌLÚ YENAKIEVE—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní March 3, 2015, àwọn ológun ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi kọ́kọ́rọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà lé àwọn lọ́wọ́ káwọn lè máa fi ibẹ̀ ṣe bárékè àwọn.

ÌLÚ HORLIVKA—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní July 25, 2016, àwọn ọkùnrin tó dira ogun wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní No. 9 ládùúgbò Simferopolska, wọ́n sọ pé ẹ̀sìn mẹ́ta ni òfin fọwọ́ sí lágbègbè yẹn, pé àwọn sì fẹ́ ṣe é táwọn èèyàn ò fi ní “gbúròó àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ́.”

Àgbègbè Luhansk

Ìlú Antratsyt, No. 4, Àdúgbò Komunarska

ÌLÚ ANTRATSYT—Àwọn aráàlù ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní September 2014, ẹ̀ẹ̀mejì làwọn èèyàn wá fọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí, a ò sì mọ àwọn tó ṣe é. Wọ́n jí ẹ̀rọ tó ń báná ṣiṣẹ́ tó wà níbẹ̀, wọ́n sì kọ ọ́ sára ògiri pé, “Àwọn Ọmọ Ogun Cossack!”

  • Ní September 25, 2014, iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n kan nílùú náà ròyìn pé àwọn kan ti gba Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan, wọ́n sì ti ń lo ibẹ̀ fáwọn nǹkan míì, bí iléèwé jẹ́lé-ó-sinmi.

  • Ní May 2015, wọ́n dá ilé náà pa dà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìlú Rovenky, No. 84-A, Àdúgbò Dzerzhynskoho

ÌLÚ ROVENKY—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní September 23, 2014, àwọn ológun látinú ẹgbẹ́ St. George Battalion ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, wọ́n sì ní àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò gbọ́dọ̀ pa dà wá. Wọ́n wá fi ibẹ̀ ṣe bárékè wọn.

  • Ní August 2015, wọ́n dá ilé náà pa dà fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÌLÚ PEREVALSK—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní November 5, 2014, Igbákejì Ọ̀gá Àwọn Ológun kó àwọn ọkùnrin tó dira ogun lẹ́yìn wá sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà, wọ́n sì sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ pé àwọn máa gba ilé náà, láti fi ṣe ibi táwọn á ti máa jẹun. Ọkùnrin tó jẹ́ igbákejì náà sọ pé, “Ó ti tán fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ó wá sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí pé wọn ò ní lè ṣe ẹ̀sìn wọn mọ́.

Ìlú Krasnyi Luch, No. 37, Àdúgbò Radianska

ÌLÚ KRASNYI LUCH—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní December 5, 2014, àwọn ọkùnrin tó dira ogun ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba náà. Wọ́n wá ń ṣọ́ ilé náà, wọ́n sì páàkì mọ́tò àwọn ológun sínú ọgbà.

ÌLÚ BRIANKA—Àwọn ológun ló gba Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí.

  • Ní March 26, 2015, àwọn ọkùnrin tó dira ogun ya wọ Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí. Wọ́n kó gbogbo tábìlì àti àga tó wà nínú ilé náà, wọ́n yọ pátákó tí wọ́n kọ “Gbọ̀ngàn Ìjọba” sára rẹ̀ kúrò, wọ́n wá fi òmíì rọ́pò rẹ̀. Ohun tí wọ́n kọ sára àmì náà ni, “Aláyélúwà Don Host.