Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 30, 2019
UZBEKISTAN

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Wá Sáwọn Ibi Tá A Ti Ṣe Ìrántí Ikú Kristi Káàkiri Orílẹ̀-Èdè Uzbekistan

Ọ̀pọ̀ Èèyàn Wá Sáwọn Ibi Tá A Ti Ṣe Ìrántí Ikú Kristi Káàkiri Orílẹ̀-Èdè Uzbekistan

Látọdún bíi mélòó kan báyìí, April 19, 2019 nìgbà àkọ́kọ́ táwọn ará wa káàkiri orílẹ̀-èdè Uzbekistan ṣe Ìrántí Ikú Kristi tí ọ̀pọ̀ èèyàn sì láǹfààní láti wá síbẹ̀.

Ìlú Chirchik tó wà nítòsí ìlú Tashkent nìkan ló forúkọ ẹ̀sìn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní gbogbo orílẹ̀-èdè Uzbekistan. Láwọn ọdún tó kọjá, ńṣe làwọn ará wa tí kò sí ní ìlú Chirchik máa ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní bòókẹ́lẹ́ káwọn ọlọ́pàá má bàa dà wọ́n láàmú. Àmọ́ lọ́dún yìí, àwọn ará sọ fáwọn Ọlọ́pàá pé àwọn fẹ́ ṣe Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n sì pè wọ́n pé kí wọ́n wá. Àwọn ọlọ́pàá náà fèsì tó dáa, wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ láti pèsè ààbò tó yẹ fáwọn tó wá síbi Ìrántí Ìkú Kristi. Àní láwọn ibì kan, àwọn ọlọ́pàá wà lára àwọn tó wá gbọ́ àsọyé.

Arákùnrin Mark Sanderson tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní ìlú Chirchik, bẹ́ ẹ ṣe rí i nínú àwòrán tó wà lókè yìí. Wọ́n túmọ̀ àsọyé náà sí èdè Russian. Àwọn tó wá jẹ́ ogọ́rùn-ún méje àti mọ́kànlélọ́gọ́rin (781). Lẹ́yìn ìpàdé àkọ́kọ́ yìí, wọ́n ṣe ìpàdé méjì míì nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba náà.

Lásìkò ìbẹ̀wò yìí, Arákùnrin Sanderson pẹ̀lú Arákùnrin Paul Gillies láti oríléeṣẹ́ wa àtàwọn arákùnrin méjì láti Central Asia ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn ọ̀gá ní Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ àti ní Ọ́fíìsì Àwọn Tó Ń Bójú Tó Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Nínú ìpàdé náà, wọ́n ní kí àwọn ará wa ṣàlàyé àwọn ohun tá a gbà gbọ́ àti ètò wa. A retí pé ohun táwọn aláṣẹ náà ti mọ̀ nípa wa máa mú kí wọ́n ṣèrànwọ́ láti forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ láwọn agbègbè tó kù lẹ́yìn ìlú Chirchik, èyí sì máa mú kó rọrùn fáwọn ará láti lè ní àwọn ibi tí wọ́n á ti máa jọ́sìn.

Arákùnrin Mark Sanderson pẹ̀lú àwọn ará tí wọ́n rán lọ rèé ní ìta Ilé Iṣẹ́ Ètò Ìdájọ́ Orílẹ̀-èdè Uzbekistan

Ìrántí Ikú Kristi tí ọ̀pọ̀ èèyàn wá àti ìpàdé tá a ṣe pẹ̀lú àwọn aláṣẹ yìí jẹ́ ohun tuntun tó wáyé ní Uzbekistan. Láti oṣù mẹ́fà báyìí, kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tí wọ́n ya wọlé rẹ̀ tàbí tí wọ́n ní kó sanwó ìtanràn tàbí táwọn ọlọ́pàá mú. Ní nǹkan bí ọdún kan sẹ́yìn, ní May 14, 2018, Ọ̀gbẹ́ni Javlon Vakhabov tó jẹ́ aṣojú orílẹ̀-èdè Uzbekistan lọ́dọ̀ ìjọba Amẹ́ríkà sọ ní lójú ọ̀pọ̀ èèyàn pé àwọn aṣòfin máa rí sí i pé wọ́n ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ kó lè rọrùn fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ lábẹ́ òfin.

Àdúrà wa ní pé kí Jèhófà bù kún ìsapá àwọn ará wa ní Uzbekistan bí wọ́n ṣe ń ‘gbé ìgbé ayé tó pa rọ́rọ́ nìṣó pẹ̀lú ìbàlẹ̀ ọkàn, tí wọ́n sì ń fi gbogbo ọkàn wọn sin Ọlọ́run.”—1 Tímótì 2:2.