APRIL 21, 2021
VENEZUELA
Ìrántí Ikú Kristi Ọdún 2021—Fẹnẹsúélà
Láìka Ọ̀pọ̀ Ìṣòro Táwọn Ará ní Fẹnẹsúélà Ń Kojú, Wọ́n Ṣe Ìrántí Ikú Kristi, Wọ́n Sì Pe Àwọn Míì Láti Dara Pọ̀ Mọ́ Wọn
Ohun tójú àwọn ará wa ní Fẹnẹsúélà ń rí kì í ṣe kékeré. Bí àpẹẹrẹ, ọrọ̀ ajé ti dẹnu kọlẹ̀, rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri ò sì jẹ́ káwọn èèyàn rímú mí. Kò tán síbẹ̀ o, àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà náà ṣì ń jà ràn-ìn. Láìka gbogbo èyí sí, àwọn ará wa rí i dájú pé àwọn ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ìyẹn nìkan kọ́ o, wọ́n tún pe àwọn míì láti dara pọ̀ mọ́ wọn.
Bí àpẹẹrẹ, ọ̀sẹ̀ méjì ṣáájú ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jà ní La Victoria, Ìpínlẹ̀ Apure, nítòsí ibodè orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà. Ìjà yẹn le débi pé gbogbo àwọn ará tó wà níjọ tó wà ládùúgbò yẹn ló sá lọ sí Kòlóńbíà. Àwọn ará tó wà níjọ Arauquita lórílẹ̀-èdè Kòlóńbíà ran àwọn ará tó wá láti Fẹnẹsúélà lọ́wọ́ kí wọ́n lè gbádùn Ìrántí Ikú Kristi látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì.
Àdúgbò kan tí tẹlifóònù àti Íńtánẹ́ẹ̀tì ò ti ṣiṣẹ́ dáadáa ni ìjọ kan ní Ìpínlẹ̀ Falcón wà. Torí náà, ẹ̀rọ kan tí wọ́n máa ń pè ní walkie-talkie ni wọ́n fi tàtagbà àsọyé Ìrántí Ikú Kristi sí àwọn àádọ́rin (70) akéde tó wà níjọ yẹn.
Arábìnrin kan sọ pé: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè rí àwọn ará wa, a ò sì lè gbá wọn mọ́ra, síbẹ̀ à ń gbóhùn wọn. Ṣe ló dà bíi pé a jọ wà pa pọ̀.”
Láwọn ọjọ́ tó ṣáájú Ìrántí Ikú Kristi, àwọn ará sapá láti kàn sí àwọn tó ń gbé láwọn ibi tó wọnú gan-an lórílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n lè gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Onírúurú nǹkan ni wọ́n ṣe káwọn èèyàn lè gbọ́ àsọyé náà. Kódà, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ìkésíni ni wọ́n fi ránṣẹ́. Ó dùn mọ́ni pé ìsapá wọn sèso rere. Bí àpẹẹrẹ nílùú Araya, ohun tó ju ọgọ́rùn-ún èèyàn ló gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi lórí fóònù.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì Fẹnẹsúélà tún ṣètò pé kí iléeṣẹ́ rédíò méjìlélọ́gọ́rin (82) àti iléeṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n mẹ́sàn-án gbé ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìrántí Ikú Kristi sáfẹ́fẹ́. Ohun tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́jọ (8,000) àwọn ará àtàwọn míì tá a pè ló gbádùn ètò náà lọ́nà yìí. Kódà, wọ́n gbé ètò yìí sáfẹ́fẹ́ láwọn èdè bíi Guahibo, Pemon, Piaroa, Pumé, Warao, Wayuunaiki àti Yekuana.
Nílùú Guasipati, Ìpínlẹ̀ Bolívar, wọ́n ṣètò láti gbé àsọyé Ìrántí Ikú Kristi sáfẹ́fẹ́ lórí rédíò láago mẹ́fà ààbọ̀. Àmọ́ iná wọn máa ń ṣe ségesège ládùúgbò yẹn. Torí èyí, àwọn kan ò ní lè gbọ́ àsọyé náà látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Àmọ́ ohun kan ṣẹlẹ̀ tó yani lẹ́nu. Iléeṣẹ́ rédíò yẹn ní ìṣòro kan, ìyẹn sì mú kí wọ́n máa gbé àsọyé náà sáfẹ́fẹ́ léraléra, kódà ó ju ẹ̀ẹ̀mẹwàá lọ tí wọ́n gbé àsọyé yìí sáfẹ́fẹ́ lálẹ́ ọjọ́ yẹn. Torí náà, gbogbo àwọn tí wọ́n ṣí rédíò wọn sí ìkànnì iléeṣẹ́ náà ló gbọ́ àsọyé yẹn látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ìdí ni pé tí iná wọn ò bá tiẹ̀ jẹ́ kí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ àsọyé náà tán, tí àsọyé yẹn bá tún bẹ̀rẹ̀, iná á ti dé láti gbọ́ ọ tán. Ìwádìí fi hàn pé ohun tó ju ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) àwọn èèyàn ló gbọ́ àsọyé náà lọ́nà yìí. Arákùnrin kan tiẹ̀ sọ pé: “Jèhófà ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pàdánù àsọyé pàtàkì yìí!”
Láìka ‘oríṣiríṣi àdánwò tó kó ìdààmú bá’ àwọn ará wa sí, wọ́n “ń yọ̀ gidigidi” bí wọ́n ṣe ń rí ìbùkún Jèhófà lórí ìsapá wọn láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, tí wọ́n sì ń pe àwọn míì.—1 Pétérù 1:6, 7.