Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn ará wa ní Fẹnẹsúélà kò dẹwọ́ nínú ìjọsìn wọn, wọ́n ń lọ sípàdé, wọ́n sì ń lọ sóde ẹ̀rí.

NOVEMBER 5, 2018
VENEZUELA

Fẹnẹsúélà: Ìgbàgbọ́ Wọn Ò Yẹ̀ Bí Nǹkan Tiẹ̀ Ń Burú Sí I

Fẹnẹsúélà: Ìgbàgbọ́ Wọn Ò Yẹ̀ Bí Nǹkan Tiẹ̀ Ń Burú Sí I

Bí ètò ọrọ̀ ajé ṣe túbọ̀ ń dẹnu kọlẹ̀ ní Fẹnẹsúélà nípa lórí àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni ìròyìn nípa àwọn ará wa tí wọ́n hùwà ọ̀daràn sí ń dé ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Fẹnẹsúélà. Bákan náà, ọ̀pọ̀ Gbọ̀ngàn Ìjọba lórílẹ̀-èdè náà ni wọ́n ti jí àwọn nǹkan tó wà nínu rẹ̀ kó lọ. Àwọn ará wa ń fara dà á bó tiẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ló ti gbówó lérí, bẹ́ẹ̀ ni kò sí oúnjẹ, oògùn àtàwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì míì. Látọdún 2013, ó lé ní ọ̀kẹ́ kan (20,000) akéde tó ti sá lọ sáwọn orílẹ̀-èdè míì bí, Ajẹntínà, Brazil, Chile, Kòlóńbíà, Ecuador, Ítálì, Peru, Pọ́túgà, Sípéènì àti Amẹ́ríkà. * Láìka gbogbo ìṣòro yìí sí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogóje (140,000) Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Fẹnẹsúélà báyìí ń bá ìjọsìn wọn lọ.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Fẹnẹsúélà kò dáwọ́ dúró láti máa ṣètò ìrànwọ́ lórílẹ̀-èdè náà. Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, ọgọ́ta (60) ìgbìmọ̀ tó ń ṣètò ìrànwọ́ ló ń ṣiṣẹ́ kára láti pín oúnjẹ fáwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin. Títí di báyìí, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Fẹnẹsúélà pẹ̀lú èyí tó wà nílẹ̀ Brazil ti pín oúnjẹ tí àwọn ará kó jọ, tó sì kún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ akẹ́rù fún àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlélọ́gọ́ta (64,000) láwọn ìjọ ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún (1,497).

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Fẹnẹsúélà tún ń pèsè àwọn ohun táwọn ará nílò láti máa bá ìjọsìn wọn lọ. Lọ́dún yìí, Àpéjọ Agbègbè “Jẹ́ Onígboyà”! méjìlélọ́gọ́fà (122) ni wọ́n ṣe káàkiri orílẹ̀-èdè náà, September 2, 2018 ni wọ́n parí èyí tó kẹ́yìn lára wọn. Àpéjọ Agbègbè yìí túbọ̀ fún àwọn ará lókun gan-an nípa tẹ̀mí, ọ̀pọ̀ lára wọn ló sì tiraka gan-an kí wọ́n tó lè wá sí àpéjọ náà.

Àwọn ará ní Fẹnẹsúélà ń ṣiṣẹ́ kára láti fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tu ọ̀pọ̀ àwọn tí wàhálà ti bá lórílẹ̀-èdè náà nínú. Ní báyìí, iye ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn akéde ń darí lóṣooṣù fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ mẹ́wàá (200,000). Iye àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ń wá sípàdé ti pọ̀ sí i, àwọn ẹgbẹ̀rún méje ọgọ́rùn-ún méjì àti mọ́kàndínlọ́gọ́ta (7,259) ló sì ṣèrìbọmi.

Àwọn ìtẹ̀síwájú tí à ń rí yìí fi hàn pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló ń fún àwọn ará wa ní Fẹnẹsúélà lágbára. Àdúrà wa ni pé kí wọ́n gbára lé Jèhófà títí dìgbà tí Ìjọba rẹ̀ máa fòpin sí gbogbo wàhálà tí à ń kojú báyìí.—Òwe 3:5, 6.

Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Fẹnẹsúélà, wo fídíò Fẹnẹsúélà—Wọ́n Ní Ìfẹ́ àti Ìgbàgbọ́ Bí Nǹkan Tiẹ̀ Nira..

^ ìpínrọ̀ 2 Láwọn àkókò tí ọrọ̀ ajé àti ètò ìṣèlú ò bá fara rọ, akéde kọ̀ọ̀kàn ló máa pinnu bóyá kí òun kúrò lórílẹ̀-èdè tóun ń gbé tàbí kóun dúró. Ètò Ọlọ́run kì í pinnu fáwọn èèyàn bóyá kí wọ́n kúrò tàbí kí wọ́n dúró.​—Gálátíà 6:5.