Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 30, 2017
VENEZUELA

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nìṣó Láìfi Ọrọ̀ Ajé Tó Dẹnu Kọlẹ̀ Pè

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà Ń Kọ́ Àwọn Èèyàn Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Nìṣó Láìfi Ọrọ̀ Ajé Tó Dẹnu Kọlẹ̀ Pè

ÌLÚ NEW YORK— Kárí ayé ni àwọn oníròyìn ti ń sọ nípa wàhálà tó ń bá orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà nítorí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀. Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà sọ pé wàhálà náà ò yọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa sílẹ̀. Àwọn ìròyìn yìí ò múnú Ìgbìmọ̀ Olùdarí dùn rárá.

Àwọn adigunjalè wọ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan nígbà tí ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ ń lọ lọ́wọ́, wọ́n sì jí àwọn ẹ̀rọ̀ abánáṣiṣẹ́ àtàwọn nǹkan iyebíye míì. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn ìgbà míì wà tí àwọn ará máa ṣèpàdé ní ilé àdáni, torí pé àwọn tó ń bára wọn jà ò jẹ́ kí wọ́n rọ́nà dé Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ló wà lára àwọn tí iṣẹ́ bọ́ mọ́ lọ́wọ́ torí pé ibi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ kógbá wọlé. Ṣe ni àwọn ọ̀daràn àtàwọn jàǹdùkú tún ń dájú sọ àwọn tó níṣẹ́ ara wọn, ìyẹn lò fà á táwọn kan fi gbé okòwò wọn tà, tí wọ́n sì sá kúrò nílùú kí wọ́n lè rímú mí. Ó bani nínú jẹ́ pé, láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó kéré tán ọgọ́rùn-ún méje ó dín ogún [680] àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin ni wọ́n ti jí gbé, ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlá àti mẹ́rìndínláàádọ́jọ [13,146] nínú wọn tí àwọn adigunjalè jí nǹkan wọn, àwọn mẹ́rìnlélógóje [144] ni wọ́n sì ti fipá bá lò pọ̀ tàbí tí wọ́n fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀ fún. Èyí tó burú jù ni ohun tí ìròyìn tó dé ní August 10, 2017 sọ, pé àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mẹ́tàdínláàádọ́ta [47] ni wọ́n ti pa. Àwọn míì tiẹ̀ tún gbẹ́mìí mì torí pé wọn ò rí ìtọ́jú tó yẹ gbà.

Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń wo bí nǹkan ṣe ń lọ sí lójú méjèèjì, wọ́n ń lo lára owó táwọn èèyàn fi ṣètọrẹ láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tí wọ́n nílò oúnjẹ, ilé gbígbé àtàwọn nǹkan míì lọ́wọ́. Ìgbìmọ̀ Olùdarí tún ń bá àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì kárí ayé sọ̀rọ̀ kí wọ́n lè rí ọ̀nà tó dáa jù láti ran àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Fẹnẹsúélà lọ́wọ́, torí pé ó léwu kéèyàn sọ pé òun fẹ́ lọ síbẹ̀ lọ ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà ti yan ìgbìmọ̀ tó ń bójú tó ètò ìrànwọ́ pàjáwìrì sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, ìgbìmọ̀ tí wọ́n yàn yìí sì ń bójú tó ìgbìmọ̀ kéékèèké mẹ́rìnlélógún [24] míì káàkiri orílẹ̀-èdè náà láti pèsè ohun tí àwọn ará nílò. Kì í ṣe pé àwọn akéde tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogóje ó lé mẹ́sàn-án [149,000] tó wà ní Fẹnẹsúélà ń fara da ìpọ́njú tó lágbára “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí nìkan ni, wọ́n tún ń fi kún ìsapá wọn láti máa sọ ọ̀rọ̀ ìtùnú tó wà nínú Bíbélì fún àwọn aládùúgbò wọn. (2 Tímótì 3:1-5; 2 Tímótì 4:2) Luis R. Navas tó jẹ́ agbẹnusọ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà sọ pé: “A ò tíì lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí báyìí rí. Àwọn tó ń wá sípàdé ìjọ ti pọ̀ sí i. Ọ̀pọ̀ akéde ló ti bẹ̀rẹ̀ aṣáájú-ọ̀nà déédéé, wọ́n sì ń ṣọ́ra ṣe bí wọ́n ń wàásù. Torí pé àwọn aládùúgbò wa mọ̀ pé a ò gbè sẹ́yìn ẹnikẹ́ni àti pé a ò lọ́wọ́ sí ìwà ọ̀daràn èyíkéyìí tó ń lọ lórílẹ̀-èdè náà, wọ́n tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ ìrètí àti ìtùnú tí à ń sọ fún wọn látinú Bíbélì.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Fẹnẹsúélà á máa bójú tó ara wọn nìṣó lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, wọ́n á sì máa tu àwọn aládùúgbò wọn nínú. Kárí ayé, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin bíi tiwọn á máa tì wọ́n lẹ́yìn nìṣó, wọn ò sì ní dákẹ́ àdúrà lórí wọn.—Róòmù 12:12, 13; 2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000

Fẹnẹsúélà: Luis R. Navas, +58-244-400-5000