Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

APRIL 22, 2019
ZIMBABWE

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Jáde Lédè Shona

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Tá A Tún Ṣe Jáde Lédè Shona

Ní March 17, 2019, Arákùnrin Kenneth Cook tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí mú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a tún ṣe jáde lédè Shona níbi àkànṣe ìpàdé kan tí wọ́n ṣe ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ Harare lórílẹ̀-èdè Sìǹbábúwè. Ọdún mẹ́ta sẹ́yìn ni iṣẹ́ ìtúmọ̀ Bíbélì tá a mú jáde yìí bẹ̀rẹ̀.

Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì ààbọ̀ (2,500) àwọn ará ló wá sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà fún àkànṣe ìpàdé yìí. A ta àtagbà rẹ̀ sí ọgọ́rùn mẹ́ta ó dín márùn-ún (295) Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ mẹ́rin, iye àwọn tó sì wá síbẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélógójì (43,000). Arákùnrin kan sọ pé: “Ó wù mí kí n ti máa lo Bíbélì tá a tún ṣe náà lóde ẹ̀rí. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ rọrùn, ó sì dùn mọ́ni, èyí kìí jẹ́ kéèyàn fẹ́ gbé e sílẹ̀ tó bá ń kà á. Ọpẹ́ ni fún Jèhófà torí ẹ̀bùn yìí.”

Bíbélì tá a tún ṣe yìí máa wúlò gan-an fún ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì (38,000) àwọn ará tó ń sọ èdè Shona. Tá a bá pín mílíọ̀nù mẹ́sàn-án (9,000,000) èèyàn tó ń gbé ní Sìǹbábúwè sọ́nà mẹ́wàá, àwọn tó ń sọ èdè Shona tó nǹkan bí ìdá mẹ́jọ, torí náà Bíbélì yìí máa mú kó rọrùn fáwọn ará láti wàásù.

Bíbélì kọ̀ọ̀kan tá à ń mú jáde ń fi ẹ̀rí hàn pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ìtumọ̀ tá à ń ṣe kárí ayé. Inú wa dùn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti ń wà lóríṣiríṣi èdè àbínibí kí àwọn púpọ̀ sí i lè rí i kà.—Ìṣe 2:8.